Dino Melaye: Mi o du ipo aarẹ ni 2019

Dino Melaye Image copyright TWITTER.COM @SENATOR DINO
Àkọlé àwòrán Dino Melaye ni isẹ ọwọ awọn ọta oun ni eyi

Sinatọ to n soju aarin gbungbun Kogi, Dino Melaye ti sọ pe irọ patapata ni iwe ipolongo ibo kan to n lọ kaakiri lati polongo didu ipo aarẹ fun oun lọdun 2019.

Dino ni isẹ ọwọ awọn ọta oun ni ipolongo ọun ati wi pe iru iwa bẹẹ ko boju mu.

Dino to fi ọrọ naa lede lori ikani Twitter rẹ sọ pe awọn ti wọn n hu iru iwa bayii fẹ ba oun jẹ niwaju ile isẹ aarẹ ni.

Dino ni akin ni oun, ati pe, oun mọ asiko ti o yẹ oun ti oun ba fẹ du ipo aarẹ.

O ni oun ni gbogbo nnkan ti o pe fun lati du ipo ọun, sugbọn ti asiko ko tii to loju oun lati se bẹẹ.