Buhari yoo lọ sibi ayẹyẹ ọdun kọkanlelọgọta ni Ghana

Aarẹ Buhari Image copyright SIMON MAINA
Àkọlé àwòrán Papa isere Igbamominira orilẹede Ghana ni ayẹyẹ ọun o ti waye

Aarẹ Buhari yoo gbera sọ lọjọ aje lati lọ si orilẹede Ghana fun ayẹyẹ igbominira ọdun kọkanlelọgọta ti yoo waye ni ọjọ isẹgun to n bọ.

Aarẹ Buhari nikan ni a gbọ pe o jẹ olori ilẹ okeere ti wọn pe sibi ayẹyẹ ọun gẹgẹ bi alejo pataki.

Ni ọjọ isinmi ni oluranlọwọ pataki fun aarẹ lori eto iroyin ati ibaraalu sọrọ Femi Adesina foju ọrọ oun lede ninu atẹjade kan.

Adesina ni, yatọ si aarẹ orilẹede Ghana, Nana Akufo-Addo, Buhari nikan lo wa lori eto lati ba awọn eniyan sọrọ nibi ayẹyẹ ọun, eleyi ti ireti wa pe yoo sokunfa ibasepọ to dan mọọran sii laarin orilẹede mejeeji.

Adesina sọ pe, 'Aarẹ Buhari yoo lo anfaani ọun lati fidi ibasepọ to dan mọọran to wa laarin awọn eniyan ati ijọba orilẹede mejeeji ọun tẹlẹ mulẹ.'

Ireti wa pe aarẹ ati awọn isọngbe rẹ, ninu eyi ti a ti ri minisita fun ọrọ ilẹ okeere, Geoffrey Onyeama ati oludamọran pataki fun aarẹ lori eto aabo, Babagana Monguno yoo pada si orilẹede Naijiria lẹyin ayẹyẹ ọun lọjọ isẹgun.