EFCC: Akala se magomago biliọnu mọkanla at‘aabọ naira

Adebayọ Akala Image copyright @AkalaAdebayo
Àkọlé àwòrán Oniruuru ẹsun to nii se pẹlu kiko dukia jọ lọna aitọ ni ajọ EFCC fi kan Adebayọ Akala

Ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹede yii, EFCC, tun ti gbe gomina nipinlẹ Ọyọ nigbakan ri, Adebayọ Alao Akala atawọn meji mii yọju sile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ, to kalẹ silu Ibadan.

EFCC ni awọn eeyan yii se magomago owo to to biliọnu mọkanla ati aabọ naira.

Awọn eeyan meji yoku to n kawọ pọnyin rojọ pẹlu Akala ni kọmisọna tẹlẹ fọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nipinlẹ Ọyọ, Senator Hosea Ayọọla Agboọla ati gbajugbaja olokoowo kan nilu Ibadan, Fẹmi babalọla.

Inu apo ajọni ijọba ibilẹ ni wọn ti gbe owo sita lọna aitọ

Awọn olujẹjọ yii nkoju ẹsun onikoko mọkanla to da lori iditẹpọ, gbigbe isẹ agbase jade laisi ninu eto isuna ati irọ pipa.

Awọn ẹsun yoku ni kiko dukia jọ pẹlu owo ti wọn ri lọna aitọ ati fifi irufẹ awọn dukia yii pamọ laijẹ ki araye mọ pe awọn lo nii ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Agbẹjọro fun ajọ EFCC, Ọmọwe Obi sọ fun ile ẹjọ pe Alao Akala ati Ayọọla dijọ gbinmọ pọ lati gbe awọn owo naa jade kuro ninu apo ajọni ijọba ipinlẹ Ọyọ atawọn ijọba ibilẹ nipinlẹ naa.