Tinubu: Ọsinbajo ko gberaga pẹlu ipo giga to wa

Ọjọgbọn Ymi Ọsinbajo Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Ọpọ eeyan lo ri Ọsinbajo bii olootọ si Buhari lasiko ti aarẹ lọ gba itọju loke okun

Asaaju kan ninu ẹgbẹ oselu APC lorilẹede Naijiria, Bọla Tinubu ti sọ wipe ipo giga ko yi ise Igbakeji Aarẹ, Yẹmi Ọsinbajo pada, bẹẹ lo si tun jẹ oniwa irẹlẹ ati ẹni to jara mọ isẹ ilu.

Tinubu sọ eleyii ninu atẹjisẹ kan to kọ si Ọsinbajo lati fi to baa dunnu wipe o pe ẹni ọdun mọkanlelọgọta, to si jẹ "ẹni to fara rẹ́ ji fun idajọ ododo, otitọ ati sisẹ deede laarin gbogbo eniyan lawujọ."

O sọ wipe nigba ti Ọsinbajo wa nipo Agbejọrọ agba ati Kọmisọna feto idajọ nipinlẹ Eko, asiko yii ni ilọsiwaju ba eto idajọ nipinlẹ naa.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Asaaju ẹgbẹ oselu APC naa, to jẹ gomina tẹlẹri nipinlẹ Eko fun saa meji, wa gbadura fun igbakeji aarẹ naa, pe ko lo igbe aye rẹ yoku ninu alaafia, ilera pipe pẹlu ogbọn, imọ ati oye.

Ẹwẹ, nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ rẹ ni Abuja, Ọsinbajo sọwipe ọjọ ori oun ti gbe ojuuse n la le oun lori, atiwipe ọjọ ori ti n sun oun si ẹgbẹ awọn agbaagba to wa lawujọ orilẹede Naijiria.