Man Utd na Liverpool

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Rashford lo ṣe Liverpool basa-basa

Bọọlu mẹji ti Marcus Rashford gba sinu awọn ni Manchester United lo lati gbo ewuro s'oju Liverpool ni papa ere bọọlu Old Trafford.

Rashford jẹ bọọlu akọkọ niṣẹju kẹrinla sigba ti wọn bẹrẹ ere.

Lẹyin iṣẹju mẹwa, agbabọọlu naa tun fi ẹyọ kan kun fun awọn alejo naa.

Ikọ Manchester United gba bọọlu ju Liverpool lọ ki wọn o to lọ isimi aarin ifẹsẹwọnsẹ.

Sugbọn lẹyin igba ti wọn pada wa lati isimi ilaji asiko ifẹsẹwọnsẹ naa, Liverpool bẹrẹ sini gba bọọlu ju Man Utd lọ.

Sibẹsibẹ naa awọn ọmọ ẹgbẹ Liverpool ko ni anfani pupọ lati gba bọọlu sun mọ ile Manchester United.

Eleyi yi pada niṣẹju kẹrindinlaadọrin nigba ti Sadio Mane gba bọọlu sunmọ ile Old Trafford ti agbabọọlu Manchester, Eric Bailly, si gba sinu awọn ikọ Man Utd.

Esi ifẹsẹwọnsẹ yii ti f'ẹsẹ Man United rinlẹ nipo keji idije liigi ilẹ Gẹẹsi pelu ami ayo marundinlaadọta.

Sugbọn Liverpool wa lẹyin Man Utd pẹlu ọgọta ami ayo.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Salah ko r'ọwọ mu ninu ifẹsẹwọnsẹ naa