Aṣofi n ṣe'wadi lori gomina Kogi nipa ẹsun kikẹru ija wọlu

Sẹnatọ James Manager ati awọn ọmọ igbimọ rẹ pẹlu awọn osisẹ asọbode Image copyright iReporterOnline
Àkọlé àwòrán Awọn asofin ni ko si aaye fun wahala ati rogbodiyan mọ lorilẹede Naijiria

Ni Ọjọbọ ni ile asofin agba orilẹede Naijiria fẹnuko lati se iwadi ẹsun kan ti sẹnatọ Dino Melaye fi kan gomina ipinlẹ Kogi lẹkun arigbungbun ariwa orilẹede Naijiria, Yahaya Bello pe o n ko awọn nkan ija ogun wọle lati ilẹ okeere.

Igbimọ ti ile asofin agba orilẹede Naijiria gbe kalẹ ti bẹrẹ ọrọ isẹ rẹ bayii.

Igbimọ naa ti se ayẹwo awọn ẹru naa ni papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe nilu Abuja.

Awọn osisẹ ileesẹ asọbode lorilẹede Naijiria ni wọn ṣe afihan awọn ẹru naa fun alaga igbimọ naa, sẹnatọ James Manager, ati awọn asofin agba orilẹede Naijiria miran nibẹ.

Lara awọn ẹru naa la ti ri awọn aṣọ ologun, bata ologun, awo oju fun iriran alẹ ati awọn ẹwu ayẹta.

Image copyright IreporterOnline
Àkọlé àwòrán Sẹnatọ Melaye lo fi ẹsun yii kan Bello nile asofin agba wi pe o n ko ẹru ofin wọlu

Bi o tilẹ jẹ wi pe ofin de iru awọn ẹru bayii ti ko si si ẹni to lee ko wọ orilẹede Naijiria lai gba asẹ latọdọ ọfiisi alamojuto abo to ga julọ lorilẹede Naijiria, ohun ti iroyin n sọ ni wipe, ileesẹ asọbode ko mọ si bi ẹru yii se de ilẹ Naijiria.

Lẹyin ti awọn asọbode ti gbẹsẹ le awọn ẹru yii la gbọ wi pe olubadamọran pataki kan si gomina ipinlẹ Kogi, ajagunfẹyinti Jerry Ọmọdara sa dede yọju si ileesẹ asọbode sugbọn wọn ko daa lohun.

Sẹnatọ Dino Melaye to n soju fun ẹkun idibo iwọ oorun kogi lo pariwo ọrọ yii sita nibi ijọko ile asofin agba ni Ọjọru pẹlu ẹbẹ fun iwadi si ọrọ naa ni kanmọ-n-kia.