Emir Sanusi beere fun mimu ọwọ awọn ọba wọ awo isejọba

Emir ilu Kano Muhammadu Lamido Sanusi nduro o nsọrọ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Emir Muhammadu Lamido Sanusi ni asiko to fun awọn ijọba lẹka gbogbo lati sisẹ lori ajọ sepọ to kunna laarin ẹka isejọba ati awọn lọbalọba

Emir ilu Kano Muhammadu Lamido Sanusi, ni ara awọn ọna ti orilẹede Naijiria ni lati yẹwo lati koju rogbodiyan ati iwa idukukulaja mọni ni igbelarugẹ awọn ọba alaye gbogbo.

Nibi ayẹyẹ idanilẹkọ ti wọn gbe kalẹ lati sami ayẹyẹ ọdun kẹwa ti Oba Munirudeen Adesola Lawal gun oye gẹgẹ bii timi ti ilu Ẹdẹ, ni ipinlẹ Ọsun lẹkun iwọ oorun gusuu orilẹede Naijiria.

Emir ilu Kano Muhammadu Lamido Sanusi ni asiko to fun awọn ijọba lẹka gbogbo lati sisẹ lori ajọ sepọ to kunna laarin ẹka isejọba ati awọn lọbalọba ki awọn naa lee maa lẹnu ọrọ ninu bi ijọba se n lọ.

O ni eyi yoo tubọ mu ki akitiyan ijọba lati koju wahala igbesumọmi ati idukukulajamọni ti o n waye lorilẹede Naijiria.

Emir ilu Kano Muhammadu Lamido Sanusi amulo awọn lọbalọba lawujọ kun ara ohun to ran awọn oyinbo amunisin lọwọ lati rii wi pe alaafia jọba lawujọ lasiko naa.

Sanusi, ti Alhaji Muhammadu Muharas, Akidu Rogo ti ilu Kano soju fun ni "aiṣe amulo awọn ọbalaye n fa wahala pupọ ni eto isakoso gẹgẹbi a ti ṣe n rii bayii, pẹlu awọn ipenija eto abo gbogbo ti o n farahan."

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Muhammadu Lamido Sanusi wipe amulo awọn lọbalọba lawujọ kun ara ohun to ran awọn oyinbo amunisin lọwọ lati rii wi pe alaafia jọba lawujọ

O sọ wipe: "O di dandan ki ijọba o se ohun gbogbo letoleto pẹlu awọn lọbalọba ninu eto atunṣe iwe ofin orilẹede Naijiria ti o nlọ lọwọ, ni pataki julọ lẹka isakoso ijọba ibilẹ, eleyi ti yoo si lee mu alaafia ati idagbasoke wa."

Oludanilẹkọ pataki ni ibi ayẹyẹ naa, Ọjọgbọn Olutayo Adesina lati ẹka imọ nipa itan ni fasiti ilu Ibadan, woye wipe "ọna si jin fun orilẹede Naijiria lati de ibi afojusun rẹ lori idagbasoke nitori aisi akojọpọ eroja oselu ati ohun elo lati ko ero araalu jọ fun afojusun kan soso fun tẹrutọmọ."

O ni ọgọjọ miliọnu lawọn ọmọ orilẹede yii bayii, ọkọọkan wọn lo si n se bo se wu u eleyi ti o ni ko se lẹyin bi awọn ti wọn ṣe ijọba ṣe n ṣe ohun ti araalu ko ran wọn.

Kabiyesi Timi ti ilu Ẹdẹ, Oba Munirudeen Adesola Lawal ninu ọrọ rẹ nibẹ dupẹ lọwọ mutumuwa bẹẹ lo tẹnumọọ pe oun ko ni kuna nibi pipese idari to see mu yangan fun ilu Ẹdẹ ni gbogbo igba.