Wọn ri oku Gabriel Cruz to sọnu ninu ọkọ orogun iya rẹ

awọn obi Gabriel Cruz Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán ọjọ isinmi to kọja ni awọn obi Gabriel Cruz ke gbajare pe awọn n wa ọmọ awọn

Awọn osisẹ alaabo lorilẹede Spain sọ pe awọn ti ri oku ọmọdekunrin ọmọ ọdun mẹjọ kan ti wọn n wa lẹyin ọkọ̀ orogun iya rẹ.

Ọmọdekunrin ọun ti wọn pe orukọ rẹ ni Gabriel Cruz ni o dẹni awati ni ipari osu keji lagbegbe Almeria ni iha guusu orilẹede Spain, ti ọ̀rọ̀ ọun si ti di ti gbogbo ìlú.

Lẹyin ti wọn kede pe wọn n wa ọmọdekunrin yii, ni oun to to ẹgbẹrun mẹrin ọlọpaa ati awọn eeyan mii fara wọn lelẹ lati sawari ọmọde yii.

Lẹyin o rẹyin ni ọwọ awọn ọlọpa tẹ ale baba ọmọ ọun.

Minisita fun ọrọ abẹle ni Spain, Juan Ignacio Zoido sọ fun AFP pe, lowurọ oni ni awọn ẹsọ alaabo abẹle da arabirin ti an wi yii duro lasiko ti o n gboku ọmọdekunrin naa lọ ninu ọkọ̀ rẹ̀.

Ọjọ kẹtadinlọgbọn osu keji ni ọjọ ti wọn ri Gabriel Cruz gbẹyin nigba ti o kuro lọdọ iyaagba rẹ̀ lati lọ si ọdọ awọn ọrẹ rẹ̀ ni abule Las Hortichuelas lagbegbe Níjar.

Awọn ọlọpaa agbegbe naa sọ pe, lati igaba ti ọrọ ọun ti sẹlẹ̀ ni awọn ti n sọ Ana Julia Quezada to jẹ ale baba ọmọ naa Angel Cruz.

Minisita fun ọrọ abẹle ọgbẹni Zoido sọ lori ikanni Twitter rẹ pe, oun ti ransẹ ibanikẹdun si iya ati baba ọmọ to salaisi ọun lorukọ ijọba ati awọn eniyan Spain, o si ni ki ẹnikẹni ma se itankalẹ ọrọ naa lọna aitọ titi iwadii awọn ọlọpaa yoo fi kẹsẹjari.

Bakan naa, olori ijọba ilẹ Spain Mariano Rajoy naa ba awọn eniyan Spain, paapaa awọn obi Gabriel Cruz kẹdun lori adanu ọun.