Aarẹ Buhari ṣ'abẹwo si ipinlẹ Benue lọjọ aje

Aarẹ Muhammadu Buhari Image copyright @BashirAhmaad
Àkọlé àwòrán Buhari yoo ṣ'abẹwo si Benue loni

Awọn eeyan ipinlẹ Benue ti gbalejo Aarẹ Muhammadu Buhari pẹlu bi o se bẹrẹ abẹwo ọlọjọ kan si ipinlẹ naa lọjọ aje.

Ninu ọrọ ti o fi si oju opo ayelujara Twitter rẹ, oluranlọwọ fun aarẹ Buhari lori ẹrọ igbalode ati iroyin, Basir Ahmad fi idi rẹ mulẹ wipe Aarẹ yoo ṣe ipade pẹlu ọba ẹya Tiv nipinlẹ Benue , Tor Tiv Ọjọgbọn James Ayatse ati alaga awọn igbimọ lọbalọba ni ipinlẹ naa.

Atẹjade naa wipe Aarẹ Buhari yoo tun ṣe'pade ajọṣepọ pẹlu awọn alẹnulọrọ gbogbo ati awọn aṣoju agbegbe ati ẹkunjẹkun nipinlẹ Benue lori eto aabo.

Bakannaa, ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu ileeṣẹ BBC, agbẹnusọ fun ijọba ipinlẹ Benue, Tever Akase sọ wi pe ijọba ipinlẹ Benue gbalejo Aarẹ Muhammadu Buhari pẹlu ireti wipe abẹwo rẹ yoo dẹkun ikọlu, iwa ipaniyan ati ija laarin awọn agbẹ oloko ati darandaran Fulani nipinlẹ naa.

Ṣaaju abẹwo yii, Aarẹ Buhari ti ṣe abẹwo si ipinlẹTaraba ati Plateau nibi ti o ti jiroro lori ọna ati dẹkun wahala gbogbo to n sẹyọ nibẹ.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: