Ile aṣofin: Jubrin maa pada bọ wale

Asofin Abdulmumini Jubrin Image copyright @AbdulAbmJ
Àkọlé àwòrán Ọ́pọ igba ni Abdulmumini Jubrin ti sọrọ tako awọn asofin to jẹ ọkan lara wọn

Ile asoju-sofin ni Naijiria ti pe alaga igbimọ ile tẹlẹ feto isuna, Abdulmumini Jubrin pada sibi ijoko rẹ lẹyin asẹ 'lọ rọọkun nile na' ti wọn pa fun-un.

Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ kejidinlọgbọn osu kẹsan ọdun 2016 n'ile pasẹ fun asofin ọhun pe ko lọ rọọkun nile na fun ọgọsan ọjọ.

Niwọn igba to si jẹ pe ẹẹmẹta lọsẹ kan n'ile njoko, o jasi wi pe osu mẹtadinlogun ni asofin Jubrin lo n'ile, ki wọn to pee pada.

Lasiko ti wọn ni ki Jubrin lọ rọọkun n'ile, gẹgẹ bii asofin Nicholas Ossai se daba rẹ, ti gbogbo asofin si kin lẹyin, wọn panupọ fọwọsi pe Jubrin ko lee di ipo asẹ kankan mu lasiko ile asofin to wa lode bayi.

Ẹsẹ ti Jubrin sẹ awọn asofin nigba naa ni pe o fẹsun kan gbogbo ijoko ile pe wọn se magomago ninu eto isuna, to si gbe iwe naa le awọn asofin lọwọ eyi tawọn akẹẹgbẹ rẹ fi oju wo nigba naa gẹgẹ bii iwa ibanilorukọ jẹ.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: