Idibo 2019: Awọn ọdọ sewọde nilu Abuja

Awọn ọdọ to n fẹ́honu han nilu Abuja Image copyright Kunle Adeleke
Àkọlé àwòrán Ọpọ ọdọ lo n foju sọna feto idibo 2019 lati du ipo kan tabi omii gẹgẹbii adari

Nse ni ẹnu ko gba iroyin loni nilu Abuja, tii se olu ilu Naijira nigbati ẹgbẹlẹgbẹ awọn ọdọ ya bo ile ijọba nilu Abuja lati fi ẹhonu wọn han.

Awọn ọdọ naa, ti wọn pọ niye lo n fapa janu pe aarẹ Muhammadu Buhari ko tii buwọlu ofin ti yoo faaye gba awọn ọdọ lati maa se ijọba.

Eyi kii si se igba akọkọ tawọn ọdọ yoo ya si igboro lati fi ero wọn han nitori bi ofin yii ko se tii di ohun, bakanaa ni wọn fi ẹhonu han lori ọrọ yii losu keje ọdun 2017.

Image copyright Kunle Adeleke
Àkọlé àwòrán Kii se igba akọkọ ree tawọn ọdọ yoo maa fi apa janu lori bijọba ko see tii fontẹ lu ofin ẹ jẹ kọmọde sejọba

A gbọ pe yoo to ipinlẹ bii ọgbọn tawọn ọdọ naa ti wa silu Abuja lati wa fi to ijọba leti pe awọn ko kere lati gba akoso orilẹede yii.

Nigba to nsalaye ohun tawọn ọdọ yii ri, ti wọn se nfapa janu, ẹni to nse agbatẹru iwọde naa, tii tun se asofin to nsoju ẹkun idibo Oshodi/Isọlọ nile asoju-sofin ilẹ wa, tii tun se ọmọ bibi ipinlẹ Imo, Hon Tony Nwulu ni awọn nfẹ ki Buhari fontẹ lu ofin ẹ jẹ kọmọde sejọba.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Nwulu, ẹni to tun fẹ dije gẹgẹ bii gomina nipinlẹ Imo, lo nlewaju ogunlọgọ awọn ọdọ yii, atawọn eeyan to ni ipenija ara ninu iwọde alaafia.

Image copyright Kunle Adeleke
Àkọlé àwòrán Aarẹ Muhammadu Buhari ti ko tii buwọlu ofin ẹ jẹ kọmọde sejọba lo n mu kawọn ọdọ sewọde

Ofin ẹ jẹ kọmọde sejọba yii si ni ipinlẹ bii ogun ti fontẹ lu jakejado orilẹede yii.