Adebisi Idikan: Òun ló gba Ìbàdàn sílẹ̀ lọ́wọ́ ìyà owó orí sísan

Adebisi Idikan: Òun ló gba Ìbàdàn sílẹ̀ lọ́wọ́ ìyà owó orí sísan

Asamọ to wọpọ nilu Ibadan ni pe "N o kọle mi bii ile Adebisi, esu aini kọ ile kankan niyẹ."

Itumọ rẹ ni pe, ile Adebisi to wa ni Idikan nilu Ibadan jẹ ile to gbajumọ, to tobi pupọ, to si ni ọgọrun-un yara, eyi ti ẹnikan ti ko ni owo nla lọwọ, ko lee dasa pe oun fẹ kọ rara.

Ọmọwe Busari Adebisi, tii se arole fun idile Sanusi Adebisi ni Idikan n‘Ibadan salaye, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ pe, eeyan kii sunkun wọ ile Adebisi, ko ma ba ẹrin jade.

O fi kun pe, baba oun lo tun ja fun ilu Ibadan, ti ọba wọn fi kuro ni Baalẹ lasan, to si di ọba alade, ti wọn n pe ni Olubadan ni oni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: