Oṣiṣẹbirin ọkọ ofurufu jabọ lati inu baalu

Ileese baalu naa to kalẹ si Dubai ti fidi ọrọ naa mulẹ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ileese baalu naa to kalẹ si Dubai ti fidi ọrọ naa mulẹ

Osisẹbirin ọkọ ofuru kan ti jabọ lati abajade pajawiri baalu Emirates kan ni Uganda.

Kete ti obirin naa jabọ ni papa ọkọ ofurufu ni wọn gbe lọ si ile-iwosan kan lẹgbẹ olu ilu orilẹede naa, Kampala l'Ọjọru (Wednesday).

Ọkọ-ofurufu naa to jẹ irufẹ 777 ti kọkọ balẹ, to n si n gbiyanju ati gbalejo awọn ero ko to gbera lọ Dubai nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Wọn ti n ṣe iwadi lorin nnkan to ṣ'okunfa iṣẹlẹ naa, ti awọn iroyin to takorawọn si n jade nipa iṣẹlẹ naa.

Sugbọn ileesẹ ọkọ-ofurufu naa to kalẹ si Dubai ti fidi ọrọ naa mulẹ fun ileese iroyin Khaleej Times:

"A le fidirẹ mulẹ wi pe, ọkan lara awọn oṣiṣẹ baalu wa jabọ lati ilẹkun nigba ti o n palẹmọ bi baalu to ni nọmba EK729 yoo ṣe gbera lati Entebbe lọjọ kẹrinla oṣu kẹta. Wọn gbe oṣiṣẹ to farapa naa lọ si ile-iwosan to sunmọ ju lọ.

"A n ṣe gbogbo iranwọ ati itọju fun oṣiṣẹ naa, a o si f'ọwọsowọpọ pẹlu awọn alaṣẹ lori iwadi wọn."