Awọn asofin daro Sinatọ Ali Wakili to d'oloogbe

Ali Wakili Image copyright Twitter @The Nigerian Senate
Àkọlé àwòrán Ali Wakili ni alaga igbimọ ile to n ri si fifopin si isẹ ati osi

Sinatọ to n soju guusu Bauchi, Ali Wakili lo jalaisi lọjọ abamẹta lẹyin oun ti wọn sapejuwe gẹgẹ bi aisan ranpẹ lọjọ.

Wakili jalaisi ni ẹni ọdun mejidinlogoji.

Ọpọ awọn leekanleekan lawujọ ni wọn ti daro asofin ọun, lati ori aarẹ Buhari, olori ile igbimọ asofin agba, Bukola Saraki, olori ile igbimọ asofin kekere, Yakubu Dogara ati awọn ọmọ ile igbimọ asofin miiran.

Image copyright Twitter @The Nigerian Senate
Àkọlé àwòrán Ile rẹ to wa ni Abuja ni sinatọ Wakili ti jalaisi

Nile rẹ to wa ni ilu Abuja ni a gbọ pe asaofin ọun ti jalaisi.

Wọn ti sin Wakili ni irọlẹ ọjọ ẹti si ilẹ isinku to wa ni Gudu, ni ilu Abuja.