Fashola: Ewọn lo tọ si ẹni to ba kọle to da wo

Fashola Image copyright Twitter.com
Àkọlé àwòrán Fashola ni ọrọ ile kikọ kii se oun to yẹ ki ẹnikẹni fọwọ yẹpẹrẹ mu

Minisita fun ọrọ ina mọnamọna, isẹ ode, ati ilegbee, ọgbẹni Raji Fashọla ti sọ pe, ẹjọ ẹwọn lo tọ lati maa da fun awọn agbasẹse ti wọn ba kọ ile ti ile ọun si da wo lẹyin o rẹyin.

Igbagbọ Fashola ni pe, iru awọn wonyii yoo jẹ awokọse fun awọn miiran ti wọn ko ba mọsẹ wọn bi isẹ.

Nigba to n sọrọ nibi eto kan ti ajọ oniroyin Naijiria (NAN) gbe kalẹ ni Fashọla sọrọ ọun.

O ni, o se pataki fun awọn agbalekọ lati rii daju pe wọn tẹle ilana ile kikọ doju gongo, ati pe, wọn gbọdọ rii pe awọn oun elo to poju owo ni wọn fi n kọ awọn ile ọun.

Fashọla tun fi kun ọrọ rẹ pe, ijọba ti n gbiyanju lati seto ilegbee ti ko ga jara fun awọn eniyan, nipa sise agbekalẹ banki ti yoo maa ri si yiyani lowo kọle (FMBN) ati ajọ NHF ti o wa ni igbọnnu ilegbee.