Vlandimar Putin jawe olubori ninu idibo Russia

Puttin Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Puttin ti wa ni ipo olori ijọba Russia lati ọdun 1999

Olori ijọba ilẹ Russia Vladimir Putin ti jawe olubori ninu idije idibo olori ijọba orilẹede Russia lẹẹkẹrin.

Gẹgẹ bi abajade idibo to waye ni kete ti awọn oludibo kuro l'awọn ibudo idibo, Putin ni ida mẹ̀talelaadọrin o le diẹ ibo ninu idibo gbogbo gbo to waye ọun.

Olori ẹgbẹ alatako to lẹsẹnlẹ ju lorilẹede Russia Alexei Navalny ni wọn ko fun laaye lati kopa ninu idije ọun.

Iroyin sọ pe, awọn ero to jade ninu idibo ọdun yii jẹ ida mẹtalelọgọta, eyi to kere si ti ọdun 2012.

Awọn fọnrọn aworan l'awọn ibudo idibo kan fi han pe, kọnu-n-kọhọ wa ninu idibo ọun l'awọn apa ibi kan lorilẹede ti ọpọ awọn fọnran ọun si safihan bi awọn osisẹ eleto idibo se n ko iwe idibo sinu apoti.

Awọn esi idibo to jade safihan rẹ pe iyatọ gboorọgboorọ lo wa laarin Putin ati awọn ti wọn jọ dije.

Sugbọn, ọpọlọpọ awọn aisedeede ni a gbọ pe o waye ninu idibo naa, lara wọn ni pe, wọn ba awọn iwe idibo ninu awọn apoti idibo kan ko to di pe awọn eniyan bẹrẹ si ni dibo, akiyesi tun wa pe, wọn fi tipa mu awọn eniyan kan lati dibo, ati pe, wọn ko fun awọn onwoye laaye lati wọle si awọn ibudo idibo kan.

Àkọlé àwòrán Putin lewaju pẹlu ọpọlọpọ ibo

Ninu iwoye tirẹ, olori ajọ eleto idibo nilẹ Russia, Ella Pamfilova sọ pe, ko tii si akọsilẹ kankan fun aisedeede ninu idibo to waye ọun.