Facebook wọ gau lori aawọ data

Mark Zuckerberg Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Wọn lo iroyin awọn eniyan lati se ranwọ fun idibo Aare Ilẹ Amẹrika Donald Trump

Awọn oloṣelu ni orilẹede Amerika, Yuroopu ati Ilẹ Gẹẹsi ti kan si awọn alaṣẹ oju opo idọrẹ lori itakun agbaye, Facebook lati ṣalaye lori bi ileeṣẹ Cambridge Analytica ṣe ni akọọlẹ iroyin awọn eniyan lai gba aṣẹ latọdọ wọn.

Awọn Senatọ ni Amẹrika pe adari Facecook, Mark Zuckerberg lati wa salaye nile igbimọ asofin lori ọna to maa gba lati daabo bo akọsilẹ iroyin awọn eniyan to wa lori Facebook.

Bakan naa, adari ile igbimọ asofin nilẹ Yoroopu, European Parliament sọ wipe awọn yoo se iwadi lori bi wọn se si iroyin ti awọn eniyan fi soju opo Facebook lo.

Agbenusọ fun olootu Ijọba Ile Gẹẹsi, Theresa May, sọ wipe ọrọ naa kan oun lominu nigba to gbọ nipa isẹlẹ yii.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Ni opin ọse, awọn ileesẹ iroyin ilẹ Amẹrika meji, The Guardian ati The New York Times fi awọn iroyin sita to fihan wipe Facebook ko se gbogbo ohun to yẹ ko se lati daabobo awọn ohun to jọ mọ iroyin ti awọn eniyan fi si oju opo wọn.

Amọ, ile-isẹ Facebook ati Cambridge Analytica sọ ninu idahun wọn wipe awọn ko se ohun ti ko tọ

Bi o se le da abo bo iroyin rẹ lori Facebook:

  • Ẹma sọra fun awọn ẹrọ igbalode ti wọn maa n bere awon nọmba ti ẹ fi n si oju opo Facebook yin.
  • Ẹlo "ad blocker" lati din awon ipolongo ku lori ẹrọ ayelujara.
  • Ẹ tun le wo awon iroyin yin ti Facebook ni, ti ẹ ba lọ si "setting" lori oju opo naa.