Ikọlu Dapchi: Awọn akẹkọbinrin ti wọn ji gbe pada de

Awọn ọmọ ileewe joko ni gbọngan nla Image copyright Yobe state governmentt
Àkọlé àwòrán Aadọfa akẹkọbinrin ni Boko Haram ji gbe lọ nilu Dapchi losu kan sẹyin

Iroyin to ntẹ wa lọwọ lati ipinlẹ Yobe ni ilu Dapchi sọkutu wọwọ laarọ Ọjọru nigba ti ikọ Boko Haram da awọn akẹkọbinrin ti wọn ji gbe lọ losu kan sẹyin pada sile.

Obi kan, Kundili Bukar sọ fun ikọ iroyin BBC pe inu ọkọ nla kan ni wọn ko awọn akẹkọbinrin naa si, ti wọn si wa wọn wọ inu abule naa.

Akọroyin BBC nilu Abuja, Chris Ewokor, ni iroyin naa sọ pe aafin baalẹ ilu Dapchi ni wọn ja awọn akẹkọbinrin naa si nidaji oni.

Se ni ilu naa bẹrẹ si ho fun ariwo ati ayọ nla nigbati wọn foju ba awọn akẹkọ naa, ti awọn mii ninu wọn si gba ile koowa wọn lọ.

Biotilẹjẹpe ko sẹni to tii le fidi ọna tijọba gba wa idande awọn akẹkọ naa mulẹ, sugbọn a hu gbọ pe o seese ki marun ninu awọn akẹkọ naa ti jade laye.

Ọga ọlọpa nipinlẹ Yobe, Abdulmalik Sunmọnu ko tii fidi isẹlẹ yii mulẹ amọ o si nse akojọpọ iroyin ọtẹlẹmuyẹ lori rẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọpọ igba ni iwọde ti waye ni Naijiria ati lawujọ agbaye lati beere itusilẹ awọn akẹkọ Chibok ti Boko Haram gbe lọ pẹlu

Bẹẹ ba si gbagbe, aarẹ Muhammadu Buhari ti kọkọ sọ fun akọwe ijọba tẹlẹ fun orilẹede Amerika, to sabẹwo wa si orilẹede Naijiria laipẹ yii pe ijọba yoo ba awọn adunkoko mọni yii dunadura lati gba itusilẹ awọn akẹkọ Dapchi naa.

Lọgan naa si ni awọn ikọ agbebọn naa tete kuro nilu ọhun.

O ni nse lawọn akẹkọ naa nwo bii ẹni to ti rẹ, ti wọn ko si dun wo rara.