PDP: Ijọba lu Naijiria ni jibiti lori ikọlu Dapchi

Awọn akẹkọbirin Dapchi Image copyright ISAAC LINUS ABRAK
Àkọlé àwòrán PDP nkesi ileẹjọ agbaye lati sewadi isẹlẹ ijinigbe Dapchi

Ẹgbẹ oselu alatako gboogi ni Naijiria, PDP ti kesi ijọba apapọ lati salaye fawọn ọmọ orilẹede yii nipa ootọ to wa nidi isẹlẹ bi wọn se gbe awọn akẹkọ Dapchi ati bi wọn se tu wọn silẹ nitoripe ọrọ yii mu ifura lọwọ.

Bakanaa ni ẹgbẹ oselu PDP tun bu ẹnu atẹ lu ileesẹ aarẹ ati ẹgbẹ oselu APC to nsejọba lọwọ fun sise alumọ kọrọyi isẹlẹ yii lati gba awọn ọmọ Naijiria.

Ẹgbẹ oselu PDP wa kesi ajọ isọkan orilẹede agbaye ati ileẹjọ to ngbọ ẹsun iwa ọdaran lagbaye lati ri iwa ẹgbẹ oselu APC yii gẹgẹ bii iwa ọdaran si ọmọniyan , ki wọn si bẹrẹ iwadi lori rẹ.

Bakanna ni gomina ipinlẹ Ekiti, Ayodele Faayose naa ni ete lati lu awọn ọmọ Naijiria ni jibiti ni itusilẹ awọn akẹkọ Dapchi naa nitoripe ejo ijọba apapọ lọwọ ninu, bẹẹ ni ijọba apapọ mọ nipa bi wọn se gbe awọn akẹkọ naa lọ.

Image copyright Fayose twitter
Àkọlé àwòrán Aimọye igba ni Fayose ti bu ẹnu atẹ lu isejọba Buhari

Fayose wa n beere pe nibo lawọn ọlọpa ati sọja wa nigba tawọn Boko Haram wọ ilu Dapchi lati gbe awọn akẹkọ naa ati igba ti wọn wa ja wọn silẹ.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Mamora sọ wipe owo ti awọn sẹnetọ n gba ti pọju

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Emi o gba 13.5 milionu naira'

BBC: A fẹ mọ idi tijọba Eko fi kọlu akọroyin wa

O ni ere ori itage gbaa, eyiti ijọba apapọ kọ, to si kopa ninu rẹ, ni gbigbe awọn akẹkọ Dapchi ati itusilẹ wọn eyi to wa lati lu awọn ọmọ orilẹede yii ni jibiti.

Fayose ni ejo ijọba apapọ lọwọ ninu isẹlẹ Dapchi

"Se kii se ohun to ya ni lẹnu, to si jẹ ajeji pe awọn eeyan to ko awọn ọmọ yii lọ tun pada wọ ilu Bauchi laijẹ pe awọn agbofinro fura pe wọn nbọ."

O wa gbadura pe Ọlọrun yoo tu asiri awọn eeyan to wa nidi ọrọ yii laipẹ laijinna.