Ijọba apapọ: Itusilẹ akẹkọ Dapchi jẹ adehun onigun meji

Awọn awọn akẹkọbinrin Dapchi ti wọn tu silẹ pẹlu ami iboju dudu ti a fi pa oju wọn rẹ nitori idanimọ
Àkọlé àwòrán Awọn akẹkọbinrin mẹrindinlaadọfa ni wọn tu silẹ

Ijọba apapọ ti sọ wi pe awọn ko san owo itanran kankan fun awọn itusilẹ awọn akẹkọbinrin ileewe girama ni ilu Dapchi ti Boko Haram ji gbe lọ.

Minisita feto iroyin, Alhaji Lai Mohammed lo sọrọ yii nilu Maiduguri ninu ọrọ kan to ba awọn akọroyin sọ.

Alhaji Lai Mohammed ni, lọfẹ lofo ni wọn tu awọn ọmọ naa silẹ lẹyin ijiroro ati ifọrọwerọ to kunna laarin ijọba ati awọn adukukulaja to ji wọn gbe.

Àkọlé àwòrán Osu kan gbako lawọn akẹkọbinrin Dapchi lo ni ibuba Boko Haram

"Ohun to sẹlẹ ni wi pe adehun alaafia waye laarin ijọba atawọn adukukulaja yii, nitori wipe bi wọn se ji awọn akẹkọ yii gbe gan tako ilana adehun yii, eyi si lo faa ti awọn eeyan yii fi da awọn ọmọ naa pada.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Emi o gba 13.5 milionu naira'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption‘Ọmọ meji daku ninu eefi Olusosun’- Olugbe agbeegbe naa

"Irọ lasan ni iroyin yoowu to ba sọ wi pe a san owo tabi se pasipaarọ kankan pẹlu wọn."

Nibayii awọn ologun ti ko awọn akẹkọ naa le awọn ikọ ti ijọba apapọ ran lọwọ nilu Maiduguri.

Ileesẹ ologun fa awọn akẹkọ Chibok to gba itusilẹ le ijọba apapọ lọwọ

Adari ikọ ọmọogun to n mojuto eto aabo lẹkun ila oorun ariwa orilẹede Naijiria, (Operation Lafiya Dole) Ọgagun Rogers Nicholas lo fa awọn ọmọbinrin naa le ikọ ọhun lọwọ.

Awọn akẹkọbinrin naa ni wọn ti ko lọ siilu Abuja bayii nibi ti ireti wa wi pe Aarẹ Muhammadu Buhari yoo ti gba wọn lalejo lọjọọbọ.