Buhari gbera lọ si Zamfara

Aarẹ Buhari n juwọ lẹnu ọna baluu rẹ Image copyright @BashirAhmaad
Àkọlé àwòrán Saaju ni Aarẹ Buhari ti lọ si ipinlẹ mẹta kan

Gẹgẹbii ara akọọlẹ eto rẹ lati lọ kaakiri awọn ipinlẹ ti ikọlu ti waye kaakiri orilẹede Naijiria, aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari yoo tẹsiwaju lọ si ipinlẹ Zamfara lọjọbọ.

Ireti wa wipe Aarẹ Buhari yoo sepade apero pẹlawọn asiwaju igun ati ẹkun gbogbo nipinlẹ naa.

Ni osu keji ọdun 2018 lawọn agbebọn tawọn eeyan funrasi pe o seese ki wọn jẹ darandaran fulani kọlu iletoBirane nijọba ibilẹ Zurmi ti wọn si gba ẹmi lẹnu awọn eeyan ti ko din ni ogoji.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Saaju abẹwo rẹ si ipinlẹ Zamfara, aarẹ Buhari ti bẹ ipinlẹ Taraba, Yobe ati Benue wo.