Isẹlẹ Eko: Iya ọlọmọ mẹrin ku sile ale

Stephen Uwa Image copyright Punch newspaper
Àkọlé àwòrán Stephen ni inu lasan ni obinrin naa ni o nrun oun

Ọkunrin kan, Stephen Uwa, tii se ẹni ọgọta ọdun, ti nnaju lolu ileesẹ ọlọpa to wa nipinlẹ Eko lori ẹsun pe arabinrin kan, Joy Vincent, ẹni ọdun marundinlaadọta jalaisi ninu ile rẹ to wa ni opopona Adeniji, ladugbo Iyana Ishashi.

Ọjọ aiku ni obinrin naa lọ ki Stephen ninu ile rẹ amọ ti onitọun daa oku re pada sile rẹ to wa ni opopona Osha Arigba ladugbo Imude, to si fẹsẹ fẹẹ.

Nigba to nsalaye lori ọrọ yii, Stephen ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun ni obinrin naa wa nigba toun daa pada sile .

Ọkunrin yii atawọn gende mẹta mii la gbọ pe wọn gbe obinrin naa wa sile ninu ọkọ kan, eyi to mu ki iya alatẹ kan tete ransẹ pe ọkan ninu awọn ọmọ obinrin naa, Ikechukwu to wa nileẹkọ.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸ wo 'idanilẹkọ' ati ifọrọwanilẹwo ti Ọmọ Ibadan se pẹlu BBC
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLadọja: Ọpọ pasitọ ati Alfa ti di oloṣelu

Ni kete ti ọmọ naa de ni Stephen gba kọkọrọ yara lọwọ rẹ, to si ran pe ko lọ pe anti obinrin naa wa amọ nigba ti wọn yoo de, oku obinrin naa ni wọn ba nilẹ.

Wọn ti gbe oku obinrin naa sile igbokusi

Anti obinrin naa, Esther ti isẹlẹ yii ru loju lo si ke gbajare tọ awọn ọlọpa lọ.

Sugbọn awijare Stephen ni ọjọ aiku ni Joy de ọdọ oun, amọ nigba to di ọjọbọ, lo ni inu nrun oun, to si ni ki oun maa gbe oun lọ sile, sugbọn o ti daku nigba ti wọn yoo fi gbee dele.

Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpa ipinlẹ Eko, Chike Oti, naa fi idi isẹlẹ yii mulẹ pẹlu afikun pe wọn ti gbe oku obinrin naa lọ sibudo igbokusi to wa nile iwosan ijọba ni Badagry fun ayẹwo to yẹ.