Níl'lùú Abuja, Alágbàfọ̀ ta ọkọ̀ onibara rẹ̀, o fowó sèyawó

Alágbàfọ̀ ọkọ̀ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Alágbàfọ̀ ọkọ̀ Chaddo sọ pe awọn ẹbí oun loun kówó fun lati ra awọn oun èlò ìgbéyàwó

Arákùnrin kan tí ó n sisẹ́ àgbàfò ọkọ̀ tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ni Muhammed Chado ni ọwọ́ awọn ọlọ́pàá ti tẹ̀ nilu Abuja lori ẹ̀sùn pe o ta ọkọ̀ kan to jẹ́ ti ọ̀kan lara awọn oníbàárà rẹ̀.

Afurasi ọ̀ún ni a gbọ́ pe o n sisẹ́ pẹlu ile isẹ́ afọ ọkọ̀ kan ni agbegbe Apo níl'lùú Abuja, ko to di pe o kojú ẹ̀sùn pe o gbe ọkọ̀ oníbàárà rẹ̀ lọ, to si ta ọkọ̀ ọun ni owo tó tó ọ̀tàlénírinwódínmẹ́wàá ẹgbẹ̀rún naira.

Owó ti a wi yii ni a gbọ́ pe arákùnrin ọ̀ún fi gbéyàwó tuntun.

Abúlé kan ti wọn n pè ni Batafe ni ìpínlẹ̀ Niger ni awọn ọlọ́pàá sọ pe ọwọ́ awọn ti tẹ Chado.

Ninu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ni Chado to jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàdínlọ́gbọ̀n ti sọ pe òódúnruń ẹgbẹ̀rún naira ni oun fi se iyawo ninu owo ọ̀ún ti ouun si fowó yòókù pata sẹ́nu.

Related Topics