Donald trump: Ẹ̀yin ọmọ ilẹ̀ Liberia ilé ya

Aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump Image copyright Donald Trump/Twitter
Àkọlé àwòrán Àarẹ Amerika ẹ̀tàlélaadọ́rinlélẹ́gbẹ̀ta (839) padà sí órílẹ̀èdè Liberia

Ìjọba ilẹ̀ Amerika ti se ìpolongo wípé àwọn yóò fòpin sí ètò tó dáàbòbo àwọn ọmọ órílẹ̀èdè Liberia tó wà ní Amerika.

Ètò ààbò tóó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Àarẹ tẹ́lẹ̀rí, Bill Clinton wà nípò fi àyè gba àwọn ọmọ órílẹ̀èdè Liberia láti sisẹ́ ní Amerika láì gba àsẹ ìjọba.

Ìjọba náà gbé ètò náà kalẹ̀ nígbà fún àwọn ènìyàn tí ogun abẹ́lé ilẹ̀ Liberia tó pa ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn láti lè wá sí órílẹ̀èdè Amerika fún ìrọ̀rùn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àmọ́, nínú àtẹ̀jáde tí Àarẹ Donald Trump fi léde ní Ọjọ́ Ìsẹ́gun, àarẹ ilè Amerika náà sọwípé kòsí ogun mọ́ lórílẹ̀èdè Liberia, nítorínáà kí àwọn ènìyàn tó tó ẹ̀tàlélaadọ́rinlélẹ́gbẹ̀ta (839) padà sí órílẹ̀èdè Liberia láàárín ọdún kan.