Ìdílé Ọba Ọ̀yọ́: Ọmọ Aláàfin kò gbọdọ̀ wó gbàgede Àrẹ̀mọ

Aláàfin tìlú Ọ̀yọ́, Ọba Làmídì Ọláyíwọlá Adéyẹmí kẹta

Oríṣun àwòrán, Alaafin/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Ọba Adéyẹmí gan sọ lọ́pọ̀ ìgbà pé ipò Àrẹ̀mọ yàtọ̀, tó sì se pàtàkì nínú ìlànà oyè jíjẹ ní ìlú Ọ̀yọ́.

Ìdílé Ọba Agúnlóyè ní ìlú Ọ̀yọ́ ti ń rọ Aláàfin tìlú Ọ̀yọ́, Ọba Làmídì Ọláyíwọlá Adéyẹmí kẹta láti pàsẹ fún ọmọ rẹ̀, Akeem Adéyẹmí, tíí se aṣojú-ṣòfin pé kó maṣe wó gbàgede àwọn Àrẹ̀mọ tó jẹ́ ti àbáláyé láti kọ́ pápá ìṣeré ìdáráyá.

Àtẹ̀jáde kan tí àwọn aṣojú ìdílé náà, Azeez Ládìgbòlù, Moshood Agbábíàká, Matilda Gbádégẹṣin àti Adémọ́lá Adéládùn fọwọ́sí ní, èròǹgbà kíkọ́ pápá ìṣeré ìdáráyá náà, tí Akeem Adéyẹmí ní yóò ná òun tó mílíọ̀ọ̀nù márùúdínlọ́gọ́rin náírà, yóò pa gbàgede àwọn Àrẹ̀mọ tó jẹ́ ti àbáláyé rẹ́.

Wọ́n wá ń rọ Ọba alayé náà láti pàrọwà fun ọmọ rẹ̀ lórí ìdí tí wọn ṣe dáàbò bo gbàgede Àrẹ̀mọ tó jẹ́ ti àbáláyé náà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde náà ti wí, " Ẹniọ̀wọ̀ Samuel Johnson tíí se Òǹpìtàn ṣàlàyé pé ojúṣe àkọ́kọ́ tí ọba alayé náà gbọdọ̀ se ni kó ṣèdásílẹ̀ ipò Àrẹ̀mọ àti Ọmọọbabìnrin tàbí èyí tó fi ara pẹ́ẹ. Èyí tó túmọ̀ sí Àrólé e tìlú Ọ̀yọ́."

Ìdílé Ọba Agúnlóyè ń pe àkíyèsí ilé aòfin àpapọ̀ sí ọ̀rọ̀ náà

"Bákanáà ni Ọba Adéyẹmí ti sọ lọ́pọ̀ ìgbà pé ipò Àrẹ̀mọ yàtọ̀, tó sì ṣe pàtàkì nínú ìlànà oyè jíjẹ ní ìlú Ọ̀yọ́. Òun ni Àrẹ̀mọ Aláàfin, tí káà rẹ̀ sì wà nísàlẹ̀ Ààfin, ṣùgbọ́n ẹnu yà wá nígbàtí Akeem Adéyẹmí ń gbèrò láti wó káà náà."

Ìdílé Ọba Agúnlóyè wá ń pe àkíyèsí ilé aṣòfin àpapọ̀, ilé asòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, iléesẹ́ tó wà fún ọ̀rọ̀ àsà àti Ọba Adéyẹmí láti tètè dásí ọ̀rọ̀ yìí, kí wọn tó yí ìtàn po.