Boko Haram tún pa èèyàn mẹ́ẹ̀dógún lágbègbè Maiduguri

Aṣíwájú ikọ̀ boko haram pẹ̀lú àṣíá ẹgbẹ́ náà

Oríṣun àwòrán, Boko Haram ffVT via AFP/Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Kò tíì sí ẹní leè sọ iye ẹ̀mí tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.

Àwọn ọmọ ikọ Boko haram tún ti s'oro ni Maiduguri, olú ìlú ìpínlẹ Borno, èyí tó ṣ'okùnfà ikú èèyàn mẹ́ẹ̀dógún tí àwọ̀n míràn tó dín díẹ̀ ni àádọ́rin sì farapa.

Ìròyìn fi ìdí rẹ múlẹ pé àwọn ọmọ ogun orílẹèdè Nàìjíríà pẹlú àwọn ọmọ ẹgbẹ adúnkùkùlajà Boko haram fìjà pẹẹta láwọn ìletò kan tí kò jìnà sí ìlú Maiduguri ni alẹ ọjọ àìkú.

Àwọn òṣìṣẹ́ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní, àwọ̀n tó kú fara gbọta nígbà tí wọ́n ń gbìyànjú àti sá àsálà fún ẹ̀mí wọn.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Àwọn agbébọn náà gbìyànjú làti dojúkọ ìlú Maiduguri gangan ṣùgbọ́n àwọ̀n ọmọogun kò gbà wọ́n láàyè

Òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ ọmọogun kan ni àwọn eṣinṣin-ò-kọ kú méje ni wọ́n dira ogun kọ̀lu ìletò méjì kan níbẹ̀ tí àwọ̀n míràn sì tún kọlu ibùdó ọmọ ogun tó wà níbẹ̀.

Ó ní wọ́n gbìyànjú làti dojúkọ ìlú Maiduguri gangan ṣùgbọ́n àwọ̀n ọmọ ogun kò gbà wọ́n láàyè.

Bákan náà, àtẹjáde kan tí kọmíṣọnà ọlọpàá ní ìpínlẹ Borno, ọgbẹni Damian Chukwu fi síta fi ìdí rẹ múlẹ pé àwọn agbébọn náà kọlu ìletò mẹrin kan; Bale, Shuwari, Alikaramti àti Jimine tí gbogbo wọn wa ní ìjọba ìbílẹ Jere.

O fí kun un pé áwọn agbébọn Boko haram náà yìnbọn s'ókè kíkankíkan pẹ̀lú àdó olóró lásìkò ìkọlù wọn náà, eléyìí tó ṣokùnfà ìfarapa ọgọ́ta àwọn èèyàn tí wọ́n ti gbé lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú báyìí.

Àmọṣá, ó ní àwọn ọlọpàá àti iléeṣẹ ọmọogun ti mú kí àlááfíà padà sí agbègbè náà.

Àwọn ìròyìn míì tí ẹ tún le nífẹ́ sí: