Buhari: Ọ̀págun ìjìjàgbara fún South Africa ni Winnie

Winnie Madikizela-Mandela

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Winnie Madikizela-Mandela kó ipa takuntakun nínú ìjìjàgbara lórílẹ̀èdè South Africa kúrò nínú ìgbèkùn amúnisìn

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti ṣe àpèjúwe ikú ògbóǹtagí ajìjàgbara nnì, Winnie Madikizela-Mandela gẹgẹ bíi àdánù ńlá fún ilẹ Áfíríkà nítorí akínkanjú obìnrin ni.

Ààrẹ Muhammadu Buhari sọ ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn ìkéde ikú arábìnrin Winnie Mandela ní ọjọ́ ajé.

Ní ọjọ́ ajé ni wọ́n kéde ikú Winnie Mandela lẹ́ni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin.

Buhari tó bá àwọn èèyàn orílẹ̀èdè South Africa kẹ́dùn lórúkọ àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà, wa rọ wọ́n láti gba ìmúlọ́kànle nínú onírúurú ìdáwọ́lé olóògbé Winnie, lásìkò tó ń sa ipá tiẹ̀ fún òmìnira orílẹ̀èdè South Africa kúrò nínú ìgbèkùn un amúnisìn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Winnie Madikizela-Mandela kú lẹ́ni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin

Buhari tún ṣe àpèjúwe Winnie Madikizela-Mandela gẹgẹ bíi "Obìnrin tí ìfọkànsìn, ìdúróṣinṣin àti ìfaradà rẹ̀ kò lẹ́gbẹ́; tó gbé ọ̀págun ìjìjàgbara sókè téńté, kódà nígbàtí ọkọ rẹ̀ wà ní àhámọ́."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ó ní yàtọ̀ sí wí pé ó jẹ́ ààyò àti àwòkọṣe fún gbogbo obìnrin ilẹ Áfíríkà, Winnie Madikizela-Mandela jẹ́ àwòkọṣe fún gbogbo ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà.

Ní ọjọ́ ajé ni wọ́n kéde ikú Winnie Madikizela-Mandela lẹ́ni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin.