PDP: Ó yẹ kí òfin de APC nítorí owó ìlú tó fi gbé Bùhárí wọlé

Buhari, Tinubu ati Oyegun

Oríṣun àwòrán, @OfficialPDPNig

Àkọlé àwòrán,

Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ariwo lásán ni ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti ìjọba àpapọ̀ ń pa kiri

Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP lórílẹ̀èdè Nàíjíríà ti ké sí àjọ elétò ìdìbò, INEC pe ko yọ ọwọ́ kílàńkó ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó ń ṣèjọba kúrò láwo òṣèlú nítorí àwọn ìfihàn tó ń jáde wí pé owó àwọn jẹgúdújẹrá ni wọ́n fi ṣe aáyan ìbò ààrẹ Muhammadu Buhari.

Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ariwo lásán ni ẹgbẹ́ òṣèlú APC, ìjọba àpapọ̀ àti mínísítà fétò ìròyìn ń pa kiri.

Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP tún fún ìjọba ààrẹ Buhari ní gbèdéke ọjọ́ mẹ́ta láti fèsì sí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án pé owó ìlú tí àwọn kan jí kó ni wọ́n ná fún ìpolongo ìbò rẹ̀ lọ́dún 2015.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

PDP ní bí ààrẹ kò bá tètè sọ̀rọ̀ lórí èyí, ní mana-n-wáà làwọn yóò gbé orúkọ rẹ̀ sí òkè téńté àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn tó jí owo ìlú kó eléyìí tí kò lẹ́ja-n-bákàn nínú.

Ó ní kàkà kí iléeṣẹ́ ààrẹ àti ẹgbẹ́ òṣèlú APC ó sọ ojú abẹ ọ̀rọ̀ níkó, orúkọ àwọn tí wọ́n ń jẹ́jọ́ níwájú iléẹjọ́ lórí ẹ̀sùn ìkówójẹ ni wọ́n ń kó síta, èyí tó ní ó fihàn pé ń ṣe ni ẹgbẹ́ òṣèlú APC, ìjọba àpapọ̀ àti mínísítà fétò ìròyìn, Lai Muhammed ń fẹ̀tẹ̀ sílẹ̀ máa pa làpálàpá lórí bí wọ́n ṣe rí owó fi gbé ààrẹ Buhari sípò.

Oríṣun àwòrán, @OfficialPDPNig

Àkọlé àwòrán,

Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ariwo ìwé orúkọ àwọn tó jí owó ìlú tí ìjọba orílẹ̀èdè Nàíjíríà wa lati gbé ojú kúrò lóríi ìkùnà ìṣèjọba rẹ̀

Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní gbogbo ariwo ìwé orúkọ àwọn tó jí owó ìlú tí ìjọba orílẹ̀èdè Nàíjíríà ń pa báyí kò yẹ̀ lẹ́yín ìgbésẹ̀ láti gbé ojú àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Nàíjíríà àti àjọ àgbáyé kúrò lóríi ìkùnà ìṣèjọba rẹ̀.

PDP ní òun yóò kéde orúkọ àwọn oníjẹkújẹ nínú APC

"A mọ àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ ìṣèjọba ààrẹ Buhari tó sì jẹ́ wí pé àwọn gan ni dáwódù nínú jíjí owó ìlú, tí wọ́n jí owó ìpínlẹ̀ kóówá wọn láti ná lórí ìpolongo olówó gọbọi fún ìpolongo ìbò ààrẹ Buhari; lẹ́yìn tíààrẹ Buhari ti sọ pé òun ò lówó lọ́wọ́."