Òsèlù Èkìtì: Ọ̀pọ̀ ọmọ PDP ń rọ́ lọ sẹ́gbẹ́ òsèlú SDP

Sẹ́nétọ̀ tó ń sojú ẹkùn ìdìbò ààrin gbùngbùn Èkìtì, Fátímà Rájí Ràsákì

Oríṣun àwòrán, Rasaki / twitter

Àkọlé àwòrán,

Bí Fáyòse se fi tipá gbé igbákejì rẹ̀ lé wọn lórí gẹ́gẹ́ bíí olùdíje fún ipò gómìnà ló fàá tí wọ́n se kúrò nínú PDP

Ẹgbẹ́ òsèlú SDP ní ìpínlẹ̀ Èkìtì ti ń gbàlèjò ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú PDP tó ń ya wá sínú ẹgbẹ́ náà báyìí.

Lára àwọn èèyàn tó ya sínú ẹgbẹ́ òsèlú SDP la ti rí igbákejì gómìnà tẹ́lẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Èkìtì fún gómìnà Ayọ̀délé Fáyòse, Bísí Ọmọ́yẹni àti sẹ́nétọ̀ tó ń sojú ẹkùn ìdìbò ààrin gbùngbùn Èkìtì, Fátímà Rájí Ràsákì tó fi mọ́ akọ̀wé tẹ́lẹ̀ fún ìjọba ìpínlẹ̀ Èkìtì, Dáre Béjidé.

Gẹ́gẹ́ bíí a ti gbọ́, àwọn èèyàn yìí lọ sínú ẹgbẹ́ òsèlú SDP nítorí bí gómìnà Ayọ̀délé Fáyòse se fi tipá gbé igbákejì rẹ̀, ọ̀jọ̀gbọ́n Kọ́lápọ̀ olúsọlá, lé wọn lórí gẹ́gẹ́ bíí olùdíje fún ipò gómìnà fún ẹgbẹ́ òsèlú PDP nínú ètò ìdìbò gómìnà tí yóò wáyé ní ìpínlẹ̀ náà ní ọjọ́ kẹrìnlá osù keje ọdún yìí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ko sọna ni APC ati PDP

Níbi ìpàdé àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ tó wáyé lọ́jọ́ ajé ní ìlú Adó Èkìtì, a gbọ́ pé Ọmọ́yẹni fúnra ara rẹ̀ ló wá síbi ìpàdé náà nígbàtí Fátímà Rájí Ràsákì àti Béjidé fi asojú ránsẹ́.

Ètò ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì tó súnmọ́lé ló sokùnfà ìpàdé náà

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ìpàdé náà, Bísí Ọmọ́yẹni ní Ọlọ́run ló gbé ẹgbẹ́ òsèlú SDP kalẹ̀, ó sì ti di ẹgbẹ́ òsèlú alágbára kẹta. bákannáà ló tún fi ọwọ́ ìdánilójú sọ̀yà pé màrìwò lásán ni wọ́n tíì rí, egúngún sì ń bọ̀ lọ́nà nítorí omilẹgbẹ èrò sì ń bọ̀ láti wá darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òsèlú SDP.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn, akọ̀wé ìpolongo fẹ́gbẹ́ òsèlú SDP, Yẹmí Akínbọ̀dé tó darí ìpàdé náà ní, wọ́n pe ìpàdé náà nítorí ètò ìdìbò gómìnà tó ń bọ̀ lọ́nà, tí àwọn sì gbọdọ̀ tètè se àgbékalẹ̀ ètò, àfojúsùn àti oyè ẹgbẹ́, kí ètò ìdìbò gómìnà náà tó wọlé dé tán.