Saudi Arabia: Jí foonu ọkọ rẹ̀ wò, kóo fi ẹ̀wọ̀n jura

Ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ alágbèéká

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Kí ìyàwó sẹ́bùrú ìròyìn láti ipasẹ̀ ìtàkùn àgbáyé láì gba àsẹ jẹ́ ìwà ọ̀daràn

Ẹ̀wọ́n ọdun kan tàbí owó ìtanràn ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́tàlẹ́láàádóje dọ́là ni aya tó bá jí foonu ọkọ rẹ̀ wò yóò san ní orílẹ̀-èdè Saudi Arabia.

Èyí ni òfin tuntun kan tí wọn sẹ̀sẹ̀ gbé jáde èyí tó wà láti dáábò bo ìwà ọmọlúwàbí àti tara ẹni.

Bákan náà ni òfin yìí wà láti dáábò bo àwọn ọkọ lọ́wọ́ ìyàwó wọn.

Ní orílẹ̀-èdè Saudi Arabia, ìyàwó tó bá ń fẹ́ kọ ọkọ rẹ̀, tó sì fẹ́ gba owó ìdákọmu lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀, gbọdọ̀ fi ẹ̀rí tó dájú sílẹ̀ pé ọkọ òun ń fi ìyà jẹ òun tàbí pé ó ń se àgbèrè níta.

Bẹ́ẹ̀ sì ni fóónù ni orísun ẹ̀rì tó fẹsẹ̀múlẹ̀ fún ẹ̀sùn àgbèrè.

Nibo ni ọrọ wa de duro?

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́tàlẹ́láàádóje dọ́là ($133,000)ni owó ìtanràn

Sùgbọ́n òfin tó ń gbógun ti ìwà ọ̀daràn lórí ẹ̀rọ ayélujára ní orílẹ̀-èdè Saudi Arabia sọ pé "tóo bá fi jí fóónù wò, tàbí gba ìròyìn tàbí sẹ́bùrú ìròyìn láti ipasẹ̀ ìtàkùn àgbáyé láì gba àsẹ tó bófinmu jẹ́ ìwà ọ̀daràn."

Ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́tàlẹ́láàádóje dọ́là ($133,000) sì ni owó ìtanràn fún ìyàwó tó bá dán àsà yìí wò.

Koda, ileeṣẹ iroyin Riyadh ṣalaye siwaju pe igbesẹ yii ni wọn ni o di dandan lati dena ibanilorukọjẹ ati idunkooko mọni lọna aitọ