Interpol: A kìí lọ́wọ́ nínú òṣèlú abẹ́lé

Asofin Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, @dinomelaye

Àkọlé àwòrán,

Iléesẹ́ ọlọ́pàá ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà kéde pé òun ń wá sẹ́nètọ̀ tó ń sojú ẹkùn ìdìbò ìlà oórùn Kogí, Dino Mélayé

Àjọ ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ní àgbáyé, Interpol, ti sàlàyé pé òun kò fi Dino Mélayé sára orúkọ àwọn èèyàn tí wọn ń wá nítorí pé àwọn kìí lọ́wọ́ nínú ọ̀rọ̀ tó bá jẹmọ́ òsèlú abẹ́lé.

Bẹ́ẹ̀ bàá gbàgbé, ọjọ́ kejìdínlógún osù kẹta ni iléesẹ́ ọlọ́pàá ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà kéde pé òun ń wá sẹ́nètọ̀ tó ń sojú ẹkùn ìdìbò ìlà oórùn Kogí, Dino Mélayé, lórí ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn, tí wọn sì ti fi ọ̀rọ̀ náà tó àjọ ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ní àgbáyé , Interpol, létí.

Sùgbọ́n lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà tí iléesẹ́ ọlọ́pàá ti kéde èyí, àjọ ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ní àgbáyé kò tíì fi orúkọ Mélayé sí ara àwọn èèyàn tí wọn ń wá lójú ìtàkùn àgbáyé wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nígbà tó ń sàlàyé ìdí tí wọn fi se bẹ́ẹ̀, àjọ ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ní àgbáyé ní "òfin tó de ìsọwọ́ sisẹ́ wa ló làá kalẹ̀ pé ohunkohun tó bá níí se pẹ̀lú ètò òsèlú, iléesẹ̀ ológun, ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn àti ẹlẹ́yàmẹ̀yà ni a gbọdọ̀ yẹra fún."

Bákannáà ni Interpol fikun pé ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá kéde tẹ́lẹ̀ fáráyé pé wọ́n ń wá, ni àwọn kò ní dásí ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́ tàbí tí wọn kò bá kọ̀wé bèèrè pé kí àwọn kẹ́de irú bẹ́ẹ̀, àwọn kò níí se bẹ́ẹ̀.