Ayọ̀ Adébánjọ: Kò tọ́ sí Ọbásanjọ́ láti tọ́ka sí oníjẹkújẹ

Olóyè Olúsẹ́gun Ọbásanjọ́, ààrẹ àná lórílẹ̀èdè Nàìjíríà
Àkọlé àwòrán,

Ọ̀pọ̀ igbà ni Olúsẹ́gun Ọbásanjọ́ ti sọ̀rọ̀ àbùkù sí ìjọba Muhammadu Bùhárí

Aṣaájú fún ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re, Olóyè Ayọ̀ Adébánjọ ti ṣe àpéjúwe ààrẹ àná lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, Olóyè Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́, gẹ́gẹ́ bíi ibojì òkú tó kún fún ẹ̀gbin, tí kò sì lẹ́tọ̀ọ́ láti tọ́ka sí ẹnikẹ́ni pé ó jẹ́ oníjẹkújẹ.

Olóyè Adébánjọ bó ọ̀rọ̀ yìí lójú lásìkò ìfilọ́lẹ̀ ìwé ìtàn ayé rẹ̀ tó pè ní "Ẹ jẹ́ ká sọọ́ bó ṣe rí", èyí tí wọn fi ń sọrí ayẹyẹ ọjọ́ ìbí àádọ́rùń ọdún rẹ̀ lókè èèpẹ̀ ní ìlú Èkó.

Adébánjọ ní Ọbásanjọ́ kò jiyàn pé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún náírà péré ni òun ní nílé ìfowópamọ́ lásìkò tó ti ọgbà ẹ̀wọ̀n dé lọ́dún 1999, tó sì jẹ́ pé igbákejì ààrẹ Àtíkù Àbúbákàr àti gbajúgbajà olókoòwò nnì, Oyèwọlé Fáṣawẹ̀ ló gba òun sílẹ̀ lọ́wọ́ gbèsè.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ó ní o yẹ ẹnigbogbo kó dínwó aró, kò yẹ atọ̀sílé Ọbásanjọ́ nítorí tó bá jẹ́ àwùjọ tó gún régé ni lórílẹ̀èdè Nàìjíríà ni, kò yẹ kí irúfẹ́ àwọn èèyàn bíi Ọbásanjọ́ sì máa yọjú sí gbangba mọ́ pẹ̀lú àfikún pé ó máa ń ya òun lẹ́nu pé àwọn èèyàn sì máa ń fún Ọbásanjọ́ ní iyì láìnáání àwọn ìwà táa mọ̀ọ́ mọ̀.

Adébánjọ ní àkókò òfò àti ìbànújẹ́ ni ìsèjọba Ọbásanjọ́

"Ó dá mi lójú pé tí ìjọba rere tó jẹ́ ti aráàlú bá gun orí ìtẹ́ ní Nàìjíríà, wọn yóò gba ibùdó ìyáwèékàwé Ọbásanjọ́ tó wà ní ìlú Abẹ́òkúta lọ́wọ́ ààrẹ àná ni."

Nínú ìwé náà ni Olóyè Adébánjọ ti ṣe àpéjúwe ìṣèjọba ọlọ́dún mẹ́jọ ààrẹ àná lórílẹ̀èdè Nàìjíríà náà gẹ́gẹ́ bíi àkókò òfò àti ìbànújẹ́ pẹ̀lú àfikún pé àkọsílẹ̀ rẹ̀ kò tó pọ́nrárá.