Ìṣẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè: Ẹ̀mí ọlọ́pàá mẹ́fà bọ́ ní Ọ̀ffà

Ilé ìfowópamọ́ kan tí àwọn alọkólóunkígbe yìí fọ́

Oríṣun àwòrán, Ayobami Agboola

Àkọlé àwòrán,

Ilé ìfowópamọ́ márùn ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló faragbá nínú ìsẹ̀lẹ̀ náà

Ìlú Ọ̀ffà ní ìpínlẹ̀ Kwara wárìrì lọ́jọ́bọ, tí kowéè ké láì ha, nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè kan tó wáyé nílé ìfowópamọ́ márùn ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìlú náà.

Àwọn eeṣin kò kọ ikú adigunjalè náà, tí wọ́n tó ọgbọ̀n níye ló ṣe ọṣẹ́ láwọn báńkì náà fún wákàtí méjì àti ààbọ̀ gbáko, èyí tó sọ ọ̀pọ̀ èèyàn di opó àti ọmọ òrukàn.

Kí aráyé baà leè mọ̀ pé eré kọ́ làwọn wá ṣe, àgọ́ ọlọ́pàá tó wà ní Owódé làwọn alọkólóhunkígbe yìí ti kọ́kọ́ kí wọn kú ilé níbẹ̀, tí wọ́n sì rán àwọn ọlọ́pàá tó wà lẹ́nu iṣẹ́, àwọn èèyàn tó ní ẹjọ́ ní tésàn náà àtàwọn èèyàn míì tó wà níbẹ̀ sọ́run ọ̀sángangan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kódà, àwọn eléṣù adigunjalè yìí tún fi ọwọ́ ba àwọn ọlọ́kadà àtàwọn èèyàn míì tó ń fẹsẹ̀ gbálẹ̀ kiri àdúgbò naa lásìkò yìí, bẹ́ẹ̀ tún ni wọ́n dáná sun àwọn ọkọ̀ ọlọ́pàá àtàwọn ọkọ̀ míì tó wà ní àyíká ọlọ́pàá náà, kí ẹnikẹ́ni máá baà leè gbá yá wọn.

Àwọn Ọlọ́ṣà náà, tí wọn ṣiṣẹ́ ibi wọn láti aago márùn ún ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún sí aago mẹ́fà ku ogún ìṣẹ́jú ní ìrọ̀lẹ́ ni wọ́n kó òbítíbitì owó láwọn ilé ìfowópamọ́ bíi GTB, Zenith, Union, First Bank àti Ecobank.

Oríṣun àwòrán, Ayobami Agboola

Àkọlé àwòrán,

Ńse ni òkú èèyàn kún ilẹ̀ káàkiri ìlú Ọ̀ffà nítorí Ìsẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè náà

Bí èèyàn bá sì jẹ orí ahun, onítọ̀hún yóò wa ẹkún mu, tó bá fi ojú kan òkú ọ̀pọ̀ èèyàn nílẹ̀, tó kún ojú pópó káàkiri.

Ìròyìn tilẹ̀ sọ pé wọ́n yìnbọn mọ́ ọ̀gá àgbà báńkì kan, ṣúgbọ́n a kò leè sọ bóyá ó ṣì wà ní ààyè tàbí ó ṣì ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́.

A yóò máa mú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn yókù wá fún yín nígbà tó bá yá.