Buhari yoo sàbẹ̀wò si ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni ọjọ́ Ajé

Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Buhari ni ìrètí wà pe yoo sèpàdé pẹ̀lu olórí ijọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Theresa May

Aarẹ Muhammadu Buhari yoo kúrò ní'lùú Abuja ni ọjọ́ aje lọ si ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fun abẹ̀wo pataki.

Ninu àtẹ̀jáde kan ti agbẹnusọ fun aarẹ̀ Shehu Garba fi sita lalẹ ọjọ́ Àìkú ni wọ́n ti fojú ọ̀rọ̀ ọun léde.

Buhari ni a gbọ́ pe yoo sepade pẹlu olórí ìjọba ilẹ Gẹ̀ẹ́sì Theresa May lati jíròrò lori ìbásepọ̀ laarin orilẹede Naijiria ati ilẹ Gẹ̀ẹ́sì, saájú ipade awọn olórí ijọba ninu ajọ Commonwealth.

A gbọ́ pe yoo tun se'pade pẹ̀lú Ben van Beurden to jẹ̀ olori ile isẹ Royal Dutch lati jíròrò lori èròńgba ile isẹ Shell ati awọn alábàásepọ̀ mìíran lati fi owó tó tó bílíọ̀nù mẹ́ẹ̀dógún dọ́là dókoòwò pẹlu ile isẹ ìpọnpo lorilẹede Naijiria.

Atẹjade ọun tun sọ pe, Buhari yoo tẹ̀síwájú ninu ìjíròrò rẹ̀ pẹ̀lú pẹlu Bísọ́ọ́bù àgbà Canterbury, ẹni ọ̀wọ̀ Justin Welby lori ìbásepọ̀ to gúnmọ́ ninu ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn lorilẹede Naijiria ati lágbàááyé.

Awọn ipade miiran ni wọn tun ni yoo waye laarin aarẹ ati awọn èèkàn mìíràn nílẹ̀ẹ Gẹ̀ẹ́sì.