Aráàlú ni yóò sọ bóyá Bùhárí yóò se sáà kejì
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

PDP àti Afẹ́nífẹ́re: Sáà àkọ́kọ́ Bùhárí kò dára láti pè fún sáà kejì

Ẹgbẹ́ òsèlù PDP àti Afẹ́nífẹ́re ti korò ojú sí bí ààrẹ Muhammadu Bùhárí se tún kéde láti díje fún sáà kejì.

Gẹ́gẹ́ bíí agbẹnusọ fún Ẹgbẹ́ òsèlù PDP, Kọ́lá Ọlọ́gbọ́ndiyàn àti akọ̀wé àpapọ̀ fún ẹgbẹ́ Afẹ́nífẹ́re, Yínká Odùmákin ti wí, sáà àkọ́kọ́ Bùhárí ló kún fún ìpànìyàn. àírísẹ́se, ìsẹ́ àti òsì èyítí yóò mú káwọn ọmọ Nàíjíríà má fi dìbò fun ní ẹ̀ẹ̀kejì.

Àmọ́sá, àwọn méjèèjì gbà pé Bùhárí lẹ́tọ̀ọ́ láti gbé igbá ìbò ní ẹ̀ẹ̀kejì lábẹ́ òfin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: