Ìsẹ̀lẹ̀ Algeria: Ó tó igba ẹ̀mí tó bá bàálù tó já lọ

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMore than 250 people have been killed after a military plane crashed in Algeria, local media report.

Ó kéré tán èèyàn tí ó tó ọ̀rìnlénígba din mẹjo ti dèrò ọ̀run nínú ìsẹ̀lẹ̀ bàálù ológun tó já lórílẹ̀èdè Algeria ní àárọ̀ ọjọ́rùú.

Pápákọ̀ òfurufú tó jẹ́ tàwọn ọmọ ológun òfurufú tó wà ní Boufarik, ní ẹ̀bá olú ìlú lórílẹ̀èdè náà, Algiers, ni ìsẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ti wáyé.

Ìròyìn abẹ́lé kan sọ pé, ó kéré tán, èèyàn bíi igba ló seése kó bá ìsẹ̀lẹ̀ náà rìn.

Ọkọ̀ ìtọ́jú aláìsàn pàjáwìrì bíi mẹ́rìnlá ló wà níbi ìsẹ̀lẹ̀ náà, tí wọn sì tí ń gbé àwọn èèyàn tó farapa lọ sí ilé ìwòsàn.

Ọdún kẹrin rèé, tí bàálù ológun kan já ní lórílẹ̀èdè Algeria yìí kan náà

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Èéfín tó ń jáde láti ara bàálù ológun kan já

Àwòrán kan láti ibi ìsẹ̀lẹ̀ náà fihàn pé èéfín ń jáde láti ibi àjákù bàálù náà.

Bẹ́ẹ̀ bá gbàgbé, ọdún kẹrin rèé, tí bàálù ológun kan já ní lórílẹ̀èdè Algeria yìí kan náà, tó sì pa èèyàn mẹ́tàdínlọ́gọ́rin, tí wọn jẹ́ òsìsẹ́ ológun àti àwọn mọ̀lẹ́bí wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: