OsunElection 2018: EU, US, Uk ní ominú ń kọ òun lórí àbọ̀ ìròyìn nípa àtúndì ìbò Ọ̀sun

An eeyan to n dibo

Ajọ isọkan orilẹede nilẹ Yuroopu, EU, awọn asoju orilẹ-ede Amẹrika ati Ilu Ọba, UK, ti sọ pe awọn n kọminu lori atundi ibo to waye nipinlẹ Ọsun.

Nigba ti wọn n kede abajade iwadi wọn nidi tọpinpin ti wọn se lasiko atundi ibo naa, awọn asoju ajọ Eu, orilẹ-ede Amẹrika ati UKmẹtẹẹta naa ni, oniruuru iwa idunkooko mọni, ọyaju awọn tita abuku ẹni lo waye sawọn oludibo.

John Bray, tii se oludari ileesẹ asoju ilẹ Amẹrika ni Naijiria, ẹni to ka abọ naa lorukọ awọn yoku ni, Awọn asoju ilẹ Amẹrika, ajọ isọkan orilẹede nilẹ Yuroopu ati United Kingdom tọpinpin bi atundi ibo se lọ si lawọn agọ idibo nipinlẹ Ọsun l‘Ọjọbọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Dele Adeleke: Ǹkan tó tọ́sí Ọsun kó ni Ọsun rígbà

O ni oju awọn koro-koro si lawọn fi se mẹrin awọn isẹlẹ to nii se pẹlu iwa ọyaju sawọn oludibo ati idunkooko mọ wọn, to fi mọ iroyin nipa titabuku awọn ọmọ ẹgbẹ oselu to n tọpinpin bi ibo naa se n lọ, awọn akọroyin ati awọn olutọpinpin eto idibo labẹle.

Bray wa fikun pe, "Ominu n kọ wa, ti awọn iroyin yii si n ka wa lara, a o si tọ awọn eeyan ti ọrọ yii gberu lọ lati fi idi okodoro isẹlẹ naa mulẹ. Awa n kesi awọn eeyan to fori kata isẹlẹ aidaa yii lati bomi suuru mu."

Anfaani nla n bẹ fawọn obinrin lagbo oselu - INEC

Ninu iroyin miran ẹwẹ, àjọ elétò ìdìbò Nàìjìria, INEC ti fi dá àwọn obìnrin lójú wí pé àǹfànì aláìlẹ́gbẹ́ ńbẹ fún wọn lẹ́ka ètò òṣèlú orílẹ́èdè Nàìjíríà gẹ́gẹ́bí ó ti wà fún àwọn akẹgbẹ́ wọn lọ́kùnrin.

Alaga ajọ INEC Ọjọgbọn Mahmood Yakubu lo sọ eyi di mimọ nigba ti ikọ awọn obinrin kan ti aṣoju obinrin fun ajọ iṣọkan agbaye lorilẹede Naijiria ati ajọ ECOWAS ko sodi bẹẹ wo ni ọfiisi rẹ.

Ọjọgbọn Mahmood Yakibu ni mìmì kan ko lee mi ipinnu ajọ naa lati rii pe idagbasoke ba iye awọn obinrin to n da si kikopa lagbo ọọrọ oṣelu lorilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, INEC

Àkọlé àwòrán,

Àjọ ọ̀hún tún jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwọn kò kéde ìgbanisíṣẹ́ kankan.

O ni laipẹ yii ni ajọ naa fun awọn ẹgbẹ oṣelu tuntun ni iwe ẹri eleyi to ni yoo tun gba awọn obinrin laaye lati kopa lagbami oṣelu paapaa gẹgẹ bii alaga lawọn ẹgbẹ oṣelu tuntun ti wọn ṣẹṣẹ da sílẹ naa.

Ṣaaju ni Comfort Lamptey to lewaju ikọ naa ti kan saara si ajọ INEC fun ipa takuntakun to n ko ni idagbasoke iṣejọba awara.

Arabinrin Comfort Lamptey ni awọn obinrin lẹkun iwọ oorun Afrika yoo korajọ nilu Abuja fun apero kan laipẹ lati yanana ipenija to n dojukọ awọn obinrin lagbo oṣelu ati ojuṣe ajọ INEC ati awọn ẹgbẹ oṣelu fun idagbasoke awọn obinrin.

Bakanaa,àjọ elétò ìdìbò Nàìjìria, INEC ti sọ wi pe awọn ko fi igba kankan polongo pe aaye iṣẹ ṣ silẹ fun ẹnikẹni.

Ninu atẹjade kan to fi sita ni ajọ naa ti sọ wi pe, itanjẹ ni awọn oniroyin kan n gbe kaakiri ninu iroyin wọn pe ajọ naa n gba awọn eeyan si iṣẹ.

Iroyin n lọ lawọn ikanni iroyin ori ayelujara kan pe ẹgbẹrun lsna ọgọrun ni aaye iṣẹ to ṣi silẹ ni ajọ naa ti wọn si n polongo eeyan fun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: