Ajínigbépawó jí akọ̀wé NURTW gbé l'Óǹdó

Ibudokọ kan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Mílíọnù máàrún naira làwọn ajinigbepawo náà ń bèèrè láti túu sílẹ

Àwọn ajínigbípawó kan ti jÍ akọ̀wé ẹgbẹ́ awakọ̀ èrò, NURTW nipinlẹ Oǹdó, Comrade Kayode Agbeyagi gbé.

Iroyin taa gbọ ni wi pe ni ọjọ abamẹta ni wọn jii gbe nigba ti o n rin irinajo lati ls ki ẹbi rẹ nilu Eko.

Opopona marosẹ Akurẹ si Ileṣa ni wọn ti ri ọjs Ọgbẹni Agbeyangi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn ajinigbepawo naa ti kan si awọn mọlẹbi rẹ ti wọn sì ń bèèrè Mílíọnù máàrún naira kí wọn tó leè túu sílẹ.

Ninu idamu lawọn igbimọ iṣakoso ẹgbẹ awakọ ero wa bayii lati lee ri owo ti awọn ajinigbepawo yii n beere fun itusilẹ akọwe wọn, to ti wa ninu idubulẹ aisan ṣaaju iṣẹlẹ yii.

Akitiyan lati ri ileesẹ ọlọpaa ba sọrọ lo ja si pabo lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ.