Awọn kókó ìròyìn fuń toni: Manchester City gba ife ẹ̀yẹ EPL, L'Ọ́ṣun, àwọ̀n oníròyìn di tíṣà ọ̀sán gangan

Manchester City gba ife ẹ̀yẹ EPL

Àkọlé fídíò,

Ki ni ero ọgbẹni Pep Guardiola?

Egbẹ́ agbabọọlu Manchester City ti gba ife English Premier League, lẹyin ti Manchester United pàdánù ninu ìdíje pẹlu ẹgbẹ́ agbabọọlu West Brom pẹlu ami ayò kan si òdo.

Ìsẹ́jú kejìléláàdọ́rin ni Jay Rodriguez gba bọ́ọ́lù ọ̀ún wọnú àwọ̀n fun West Brom lẹyin ti gbogbo ìgbìyànjú Manchester United lati gba bọọlu wọnú àwọ̀n já sí pàbó.

L'Ọ́ṣun, àwọ̀n oníròyìn di tíṣà ọ̀sán gangan

Oríṣun àwòrán, Niyi Folorunso

Àkọlé àwòrán,

Àwọn oníròyìn náà kún ara ọ̀ọ́dúnrún òṣìṣẹ́ tí ìjọba dá padà sí kíláàsì

Àwọn oníròyín méjì ni ìròyìn ti fihàn pé wọ́n wà nínú nǹkan bíi ọ̀ọ́dúnrún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun tí wọ́n gbé lọ káàkiri àwọn iléèwé nípínlẹ̀ náà báyìí.

Gẹgẹbii iroyin to tẹ BBC Yoruba lọwọ ṣe sọ, alaga ẹgbẹ akọroyin ere idaraya, SWAN nipinlẹ Ọṣun, ọgbẹni Adeyẹmi Abọdẹrin pẹlu alaga ẹgbẹ awọn oniroyin obinrin, NAWOJ nipinlẹ naa, arabinrin Tunrayo Ayegbayo wa lara awọn olukọ tuntun ti ijọba ṣẹṣẹ taare sawọn ileewe rẹ.

APC kéde ìkànì ẹ̀rọ ayélujára tuntun

Oríṣun àwòrán, Twitter.com

Àkọlé àwòrán,

Ikanni Twitter naa ní àmì ìdánilójú pe APC lo nií

Lẹ́yìn ìsẹ̀lẹ̀ to wáyé lọ́jọ́ abamẹ̀ta, nigba ti ọkunrin àjòjì kan gbàkóso ikani Twitter ẹgbẹ́ oselu APC, ẹgbẹ́ ọun kede pe, oun ti ni awọn ìkànnì ìbáraẹni sọ̀rọ̀ tuntun lori ẹ̀rọ ayélujára.

Bí o tilẹ̀ jẹ́ pe ẹgbẹ́ APC ni ikanni ìbáraẹni sọ̀rọ̀ lori Twitter tẹ́lẹ̀, ẹgbẹ́ ọun sọ pe ikanni ọun kii se tàwọn, ati pe, awọn o ni ounkóhun se pẹlu ikanni ọ̀un ti o ni àdírẹ́ẹ̀sì @APCNigeria.

Ìṣẹ́jú kan BBC

Sàká: Oun tí orí bá yàn fún ẹ̀dá ni kó ṣe

Àkọlé fídíò,

Sàká: Oun ti orí bá yàn fún ẹ̀dá ni kó ṣe

Gold coast 2018: Nàìjíríà ní góòlù mẹ̀sán

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ipo kẹsan lori atẹ igbelewọn ami ẹyẹ ni Nàìjíríà wà nibi idije naa

Bí ìdíje àwọn orílẹ̀èdè tó ti fìgbàkan rí wà lábẹ́ ìmúnisìn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Commonwealth ṣe ń wá sí ìdádúró lọ́jọ́ àìkú, orílẹ̀èdèNàìjíríà ti bọ́ sí ipoò kẹsán lórí atẹ ìgbéléwọ̀n àmì ẹ̀yẹ níbi ìdíje náà.

Goolu mẹsan, fadaka mẹsan ati baaba mẹfa ni awọn oludije lati orilẹede Naijiria ti gba bayii.

Ajínigbépawó jí akọ̀wé NURTW gbé l'Óǹdó

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Mílíọnù máàrún naira làwọn ajinigbepawo náà ń bèèrè láti túu sílẹ

Àwọn ajínigbípawó kan ti jÍ akọ̀wé ẹgbẹ́ awakọ̀ èrò, NURTW nipinlẹ Oǹdó, Comrade Kayode Agbeyagi gbé.

Iroyin taa gbọ ni wi pe ni ọjọ abamẹta ni wọn jii gbe nigba ti o n rin irinajo lati ls ki ẹbi rẹ nilu Eko.

Salah, Mane fi àmì tuntun lélẹ̀ ní Premiership

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Salah àti Mane ti di èèkàn nínú ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Liverpool

Ìlúmọ̀ọ́ká agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀èdè Egypt nì, Mohammed Salah ti di agbábọ́ọ̀lù ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà tó gbá góòlù tó jẹ góòlù tó pọ̀jù ní sáà ìdíje bọ́ọ̀lù kan ní líìgì Premiership.

Goolu to gba wọle fun ikọ rẹ, Liverpool ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Bournemouth lọjọ abamẹta lo gbee lọ si tente oke pẹlu ọgbọn goolu.