Trump yóò gbàlejò Buhari nílé ìjọba

Àworan Buhari ati Trump Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìgbà àkọ́kọ́ nì yìí tí àwọn ààrẹ méjéèjì yóò máa pàdé

Ààrẹ Mùhámádù Bùhárí yóò bá akẹgbẹ́ rẹ̀ lórílẹ̀èdè Améríkà, Donald Trump lálejò ní ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù kẹrin ní ilé funfun báláú White House nílùú Washington DC.Lásìkò àbẹ̀wò náà, àwọn olórí orílẹ̀èdè méjèèjì yóò jíròrò lórí ìdàgbàsókè ètò ọrọ̀ ajé àti gbígbógun ti wàhálà ìdúnkukùlajà mọ́ni.Ilé funfun báláú White House ni ìpàdé Bùhárí ati Trump yoo mẹ́nuba àwọn ohun tí yóò mú àǹfàní bá orílèèdè kóówa wọn.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù kẹ́rin ni Buhari kéde pé òun yóò díje lẹ́ẹ̀kejì lọ́dún 2019.