INEC ń pe àwọn èèyàn lórí fóònù láti wá gba káàdì ìdìbò wọn

Awọn oṣiṣẹ ajọ INEC nipinlẹ Ọyọ

Oríṣun àwòrán, @inecnigeria

Àkọlé àwòrán,

INEC ní gbígba àwọn káádì ìdìbò tó wà nílẹ̀ ló ń fà bíi ìgbín pẹ̀lú onírúurú ìpolongo àti ìtanijí

INEC ipinlẹ Ọyọ ń fúnra wọn pe àwọn èèyàn lati wa gba kaadi idibo wọn.

Pẹlu ipenija obitibiti kaadi idibo ti awọn oludibo ko wa gba jakejado orilẹ-ede Naijiria bayii, ajọ INEC ni ipinlẹ Ọyọ ti da ọgbọn kan, eleyii ti wọn yoo maa fi pe gbogbo awọn oludibo ti kaadi idibo wọn wa nilẹ lati wa gba kaadi wọn.

Titi di oṣu kẹjọ, gẹgẹ bii Kọmiṣọna fun ajọ INEC nipinlẹ Ọyọ, Mutiu Agboke ṣe sọ laipẹ yii, lo ni o le ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin awọn kaadi idibo to ṣi wa ni ikawọ ajọ naa ti awọn to nii ko tii wa gba.

Eyi lo si faa ti ajọ INEC nipinlẹ Ọyọ fi ṣi oju opo kan silẹ fun pipe awọn oludibo lori ẹrọ ibanisọrọ lati wa gba kaadi idibo wọn ninu eto naa ti wọn bẹrẹ ni ọjọ Aje.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amofin Mutiu Agboke gan an lo n lewaju eto naa eleyi ti wọn gbe kalẹ ni olu ileeṣẹ ajọ naa nipinlẹ Ọyọ.

Nibayii ajọ INEC ṣi n kọminu lori iha kokanmi ti awọn eeyan kan n kọ si gbigba kaadi idibo wọn jakejado Naijiria, ni pataki julọ, bi eto idibo 2019 ṣe n kan lẹkun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Àjọ INEC ní mílíọ̀nù méje ni káàdì ti awọ̀n eeyan ko tii wa gba atipe

INEC, ileeṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ yóò ṣiṣẹ́ pọ̀ lórí Káàdì ìbò

Àjọ elétò ìdìbò lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, INEC, yóò fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn iléeṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká lórí ọ̀rọ̀ ìpèníjà àìwá gba káàdì ìdìbò àwọn olùdìbò.

Kọmíṣọ́nà àgbà fún ètò ìpolongo àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lábẹ́ ájọ INEC, Ọ̀gbẹ́ni Dèjì Ṣóyèbí, ló fi ọ̀rọ̀ yìí tó BBC létí pé, àjọ náà fẹ́ lo àǹfàní nọ́ḿbà ìbánisọ̀rọ̀ tí wọ́n fi sílẹ̀ lásìkò ìforúkọsílẹ wọn, láti kàn sí àwọn olùdìbò lórí ibi tí wọn yóò ti lọ gba káádì ìdìbò wọn.

Àjọ INEC ní, mílíọ̀nù méje ni káàdì ti awọ̀n eeyan ko tii wa gba, atipe, ìpínlẹ̀ Èkó làwọn tí kò tíì gba káàdì náà pọ̀ sí jùlọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Bawo ni iforukọsilẹ awọn oludibo se n lọ pelu ajọ INEC?

Ọ̀gbẹ́ni Ṣóyèbí ní, ìdádúró yóò wà lórí gbígba káàdì ìdìbò láwọn ìpínlẹ̀ tí ìdìbò yóò ti wáyé lọ́dún yìí ní oṣù kan sí àkókò ìdìbò níbẹ̀.

Kínni ó ń ṣokùnfà aigba kaadi awọ̀n oludibo ?

Ajọ INEC ni iṣipo pada awọn eeyan kun ara ohun to n faa ti ọpọ ko fi lee gba awọn kaadi wọn.

Kọmíṣọ́nà àgbà fún ọ̀rọ̀ ìpolongo àti ìdánilẹ́kọ́ lájọ INEC ni, awọn akẹkọ ati awọn agunbanirọ ni eyi kàn julọ.

Bakan naa lo tun mẹnuba iwa aibikita awọn oludibo gẹgẹ bii idi miran to n fa bi awọn kaadi yii ko ti ṣe tii ri eeyan wa gba wọn.

Igbiyanju ati iranwọ awọn ijọba ipinlẹ

Ajọ INEC ni awọn ipinlẹ gbogbo lo n gbiyanju lati rii pe awọn eeyan wọn jade lati forukọ silẹ ati lati gba kaadi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

INEC ni eto iforukọ silẹ n tẹsiwaju ṣugbọn gbigba awọn kaadi to wa nilẹ lo n fa bii igbin

O darukọ awọn ipinlẹ bii Anambra ati Ọṣun gẹgẹ bii ara awọn ipinlẹ to ti gbe igbesẹ láti fun awọn oṣiṣẹ ni isinmi lẹnu iṣẹ kí wọn lee gba kaadi ìdìbò naa.

Ju gbogbo rẹ lọ, ajọ INEC ni eto iforukọsilẹ n tẹsiwaju ṣugbọn gbigba awọn kaadi to wa nilẹ lo n fa nílẹ̀ bii igbin.

Àkọlé fídíò,

'Ilé ìwòsàn ṣi abẹ́rẹ́ Formalin gún mí; n kò lè dá ìgbẹ́ àti ìtọ̀ dúró mọ́'

Àkọlé fídíò,

Tẹniọla: Pè mí láago tí o bá mọ iyán gún pẹ̀lú ọbẹ̀ ilá tó dùn