Marcos Alonso jẹ́jọ́ lílo ìwà ipá pẹ̀lú Southampton

Aworan ifesewonse laarin Chelsea ati Southampton
Àkọlé àwòrán,

Fidio fihan wipe o seese ki Alonso duro lẹyin ẹsẹ to fun agbabọọlu fun Southampton, Shane Long

Ọkan lara awọn agbábọ́ọ́lù lọ́wọ́ ẹ̀yìn fun ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea, Marcos Alonso, ni ajọ to n risi ọrọ erebọọlu ni Ilẹ Gẹẹsi, FA, ti fẹsun kan wipe o wu iwa ipa si Shane Long lori papa ninu ifẹsẹwọnsẹ ti wọn ti na Southampton lami ayo mẹta si meji.

Ninu ifẹsẹwọnsẹ naa, fonran fidio fi han wipe, o seese ki Alonso duro lẹyin ẹsẹ to fun agbabọọlu Southampton naa ni ipele ikinni ifẹsẹwọnsẹ naa lọjọ Satide ọsẹ to kọja.

Ìrọlẹ Ọjọru ni wọ́n fún Alonso mọ láti fesi

O seese ki agbábọ́ọ́lù lọ́wọ́ ẹ̀yìn to jẹ ọmọ ilẹ Spain naa kuna, lati kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ to kangun si asekagba pẹlu Southampton lọjọ isinmi ọsẹ yii, ti wọn ba fi asẹ si ẹsun ti wọn fi kan an naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ìrọlẹ Ọjọru ni wọ́n fún Alonso mọ láti fesi si ẹsun ti wọn fi kan an naa.