Ilé asòfin àgbà: Omo-Agege ló gbé ọ̀pá àsẹ ilé lọ

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIlé asòfin àgbà: Omo-Agege ló gbé ọ̀pá àsẹ ilé

Fídíò òkè yìí ló ń se àlàyè bí awọn jàǹdùkú se yabo ilé asòfin àgbà ní ìlú Àbújá, ti wọ́n sì gba ọ̀pá asẹ ilé lọ.

Ìròyìn náà ní, lásíkò tí ìjókòó ilé ń lọ lọ́wọ́, lawọn jàǹdùkùú yìí ya wọnú ilé, tí wọn sì gbé ọ̀pá àsẹ ilé.

Wàyì ó, àtẹ̀jáde kan tí ilé asòfin àgbà ilẹ̀ wa fi síta lórí ìsẹ̀lẹ̀ náà sàlàyé pé àwọn jàǹdùkú kan yabo àwọn níbi jókòó ilé, tí asòfin kan tí wọ́n ti ní kó lọ rọọ́kún nílé ná, Ovie Omo-Agege sì ló kó sòdí, tí wọn sì gbé lọ

Image copyright @SenateNG
Àkọlé àwòrán Lásíkò tí ìjókòó ilé ń lọ lọ́wọ́, lawọn jàǹdùkùú ya wọnú ilé, tí wọn sì gbé ọ̀pá àsẹ ilé.

Ilé asòfin àgbà ilẹ̀ wá se àpèjúwe ìsẹ̀lẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bíi ìwà ọ̀daràn sí ìjọba, nítorí ó jẹ́ ète láti já ẹ̀ka kan nínú ìjọba Nàíjíríà gbà pẹ̀lú ipá.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ilé ní gbogbo àwọn ẹ̀ka agbófinró ló gbọdọ̀ dúrú sí ìhà ìlànà tó tọ́ lórí ọ̀rọ̀ yìí, kí wọn sì se kóríyá fáwọn òsìsẹ́ wọn láti gba ọ̀pá àsẹ ilé padà, kí wọn sì tún mú àwọn èèyàn tó wà ní ìdí ìsẹ̀lẹ̀ yìí.

Ilé fi kún un pe "ìwà yìí jẹ́ ọ̀yájú sí ẹ̀ka asòfin, àwọn asáájú ilé sì ti dúró láti tako ìwà burúkú yìí.