Ìjọba ìpínlẹ́ Kaduna: A kò dá olùkọ́ míì dúró

Image copyright Nasir El-Rufai/Twitter
Àkọlé àwòrán Gómínà Nasir El-Rufai bu ẹnu àtẹ́ lu ìròyìn pe àwọn dá ogunlọ́gọ́ olùkọ́ tí wọ́n sẹ̀sẹ̀ gbà ní ìpínlẹ̀ náà dúró

Ìjọba ìpínlẹ́ Kaduna ti bu ẹnu àtẹ́ lu awuyewuye tó ń lọ lóde wí pé wọ́n dá ẹgbẹgbẹrún àwọn olùkọ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà dúró.

Nínú ìgbésẹ́ láti mú jíjà ràìn-ràìn ìròyìn wálẹ̀ lórí dídá ẹgbẹ̀rún mẹ́ta olùkọ́ ilé ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ dúró látàrí àìkún ojú òṣùwọ̀n wọ́n, ìjọba ìpínlẹ́ Kaduna sọ pé àwọn olùkọ́ ilé ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀sẹ̀ gbà yìí ti ṣe tán láti lọ sí ibi tí wọ́n bá pín wọn sí láti lọ dí àlàfo tó sí sílẹ̀ níbẹ̀.

Àmóṣá, ìpínlẹ̀ náà ń dojú kọ abala ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ míì lẹ́yìn tí wọ́n ti dá gbogbo akọ̀wé ètò ẹ̀kọ́ ìpínlẹ̀ náà dúró.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: