Fayose: Ilé ẹjọ́ Supreme ló kàn lórí gbigbẹsẹ̀lé àṣùwọ̀n ìfówópamọ́sí mi

Aworan Ayo Fayose Image copyright Facebook/Lere olayinka
Àkọlé àwòrán Ayo Fayose je alatako to foju han si ijọba orilẹẹde Naijiria

Lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti ní kí ajọ to n gbogunti ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu, EFCC, ó gbẹ́sẹ̀ lé àṣùwọ̀n ìfówópamọ́sí Gómìnà Ayọ̀délé Fáyóṣe ti ìpínlẹ̀ Èkìtì, Gómìnà Fáyóṣé ti sọ pé, kò tán síbẹ̀, ilé ẹjọ́ tó ga jù lọ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà ni yóò yanjú ọ̀rọ̀ náà.

Ní ọjọ́bọ̀ ni ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn gbé ìdájọ́ kalẹ̀ pé kò tọ̀nà bí ilé ẹjọ́ gíga àpapọ̀ kan ṣe ká àjọ EFCC lọ́wọ́ kò pé kò lẹ́tọ́ láti pààlè lé àṣùwọ̀n ìfówópamọ́sí Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì ọ̀hún.

Agbẹnusọ fun Gomina Fayose, ninu ọrọ to ba awọn akoroyin sọ nilu Ado Ekiti lọjọbọ ṣalaye pe gomina Fayose yoo gba ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria lọ lati yanju ọrọ naa.

Bi a ko ba gbagbe, ni ọdun 2016, adajọ agba ti ileẹjo giga to kalẹ si Ekiti pasẹ ki ajo EFCC o gbẹsẹ kuro lori apo asuwọn rẹ mejeeji, lẹyin ti ajọ naa fẹsun kan gomina naa lori owo ribiti to wa ninu àṣùwọ̀n ìfówópamọ́sí rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: