Àwọ̀n adigunjalè pa ọlọ́pàá ní Ìfàkì Èkìtì

Ìbọn àwọn adigunjalè Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọ̀n adigunjalè pa ọlọ́pàá ní Ìfàkì Èkìtì

Àwọn adigunjalè kọlu ilé ìfowópamọ́sí kan ní ìlú Ìfàkì Ekiti nipinlẹ Èkìtì ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́bọ̀.

Nigba ti iji ikọlu wọn yoo fi dá, ẹmi ọlọpa kogberegbe kan ti lọ sii bẹẹni ọpọ awọn eeyan lo ti farapa nibi ti wọn ti n sa asala fun ẹmi wọn.

Awọn ti ọrọ naa ṣe oju wọn sọ wi pe nnkan bii agogo mẹrin lawọn firi ndi ọkẹ ẹda naa ya wọ banki kan ṣoṣo to wa ni ilu naa ti wọn sì ṣina ibọn bolẹ.

Gbogbo ẹrọ apọwo, ATM to wa ni banki naa ni wọn fi ibọn bajẹ ti gbogbo ilu naa si da paroparo ni nkan bii ọgbọ iṣẹju ti wọn fi ṣiṣẹ láabi wọn.

Bi o tilẹ jẹ wipe awọn oṣisẹ ilé ìfowópamọ́sí naa ti pari isẹ ki wọn to de, awọn adigunjale ọhun yinbọn pa ọlọpa kogberegbe, MOPOL kan ninu awọn ọlọpa to n ṣọ ibẹ.

Ẹnikeji rẹ ti ibọn ba ni wọn ti gbe lọ si ile iwosan bayii.

Ileeṣẹ ọlọpa ko tii sọrọ lori iṣẹlẹ yii.

Bi a ko ba ni gbagbe, ni ọsẹ diẹ sẹyin lawọn adigunjale ya bo ilu Offa ni ipinlẹ Kwara lati ṣe irufẹ ọṣẹ bayii.