AfricanDrumFestival: Abẹ́òkúta gbàlejò èrò fún àjọ̀dùn ìlù

Awọn obinrin kan n jo Image copyright AfricanDrumFestival
Àkọlé àwòrán Ayẹyẹ àjọ̀dùn ìlù nílẹ̀ Áfíríkà ti bẹ̀rẹ̀ nílú Abẹ́òkúta

Ayẹyẹ àjọ̀dùn ìlù nílẹ̀ Áfíríkà ti bẹ̀rẹ̀ nílú Abẹ́òkúta.

Nibi ayẹyẹ yii ni wọn ti maa n ṣe afihan ọkan o jọkan ilu iṣẹmbaye ati aṣa ilẹ Yoruba ati gbogbo Afirika.

Image copyright AfricanDrumFestival
Àkọlé àwòrán Ó lé ní ogún ìpínlẹ̀ tí yóò kópa níbi ayẹyẹ àjọ̀dùn ìlù nílẹ̀ Áfíríkà náà

Ninu ọrọ ti wọn sọ nibẹ, awọn eekan ọbalaye meji nilẹ Yoruba, Ọọni ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi Ọjaja II ati Alaafin ti ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyemi III gba awọn to wa nipo aṣẹ lẹka iṣejọba gbogbo niyanju lati rii wi pe wọn n ṣe koriya fun igbedide aṣa ilẹ Yoruba.

Image copyright AfricanDrumFestival
Àkọlé àwòrán Àgba awọn to wa nipo aṣẹ lẹka iṣejọba gbogbo niyanju lati rii wei pe wọn n ṣe koriya fun igbedide aṣa ilẹ Yoruba.

Ọọni Adeyẹye Ogunwusi ni idunnu nla lo jẹ fun awọn ọbalaye lasiko yii lati rii pe ajinde n de ba awọn aṣa ilẹ Yoruba.

Image copyright AfricanDrumFestival
Àkọlé àwòrán "Kani a mọ pataki idagbasoke aṣa si idagbasoke eto ọrọ aje wa, a o tẹpa mọ"

" Ọpọ àṣà ilẹ kaarọ oojiire ni o ti n lọ, ṣugbọn a dupẹ fun awọn ti Ọlọrun nlo lati gbee soke pada. Kani a mọ pataki idagbasoke aṣa si idagbasoke eto ọrọ aje wa, a o tẹpa mọ .

Image copyright AfricanDrumFestival
Àkọlé àwòrán Aṣa lo n siwaju ẹsin nitori aṣa lagbara ju ẹsin lọ

Aṣa lo n siwaju ẹsin nitori aṣa lagbara ju ẹsin lọ. Ilẹ kaarọ oojiire ni awokọṣe fun gbogbo agbaye.''

Image copyright AfricanDrumFestival
Àkọlé àwòrán Ọkanojọkan awọn agbaṣaga ni wọn yoo kopa nibi ajọdun naa

Ninu ọrọ tirẹ, Alaafin ti ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyemi ṣalaye pe 'aṣa jẹ ọna kan gboogi lati ṣe aato ilu. Ti a ba mu aṣa wa, a lee ko ilẹ Afirika jọ tii a o si fun wọn ni iwuri lati fi imọ ṣọkan.'

Image copyright AfricanDrumFestival
Àkọlé àwòrán Awọn ọbalaye kan sara si awọn agbaṣaga

Ni tirẹ, gbajugbaja onkọwe ni, ọjọgbọn Wọle Soyinka rọ awọn ọba alaye lati maṣe kaarẹ lori awọn oloṣelu to n ṣakoso ijọba bayii nipa gbigbawọn lamọran latigba de igba paapaa julọ lori idagbasoke aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba.

Image copyright AfricanDrumFestival
Àkọlé àwòrán Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe ileri atilẹyin fun idagbasoke aṣa

Ninu ọrọ tirẹ,Aarẹ Muhammadu Buhari ti minisita fun eto iroyin ati aṣa, Alhaji Lai Mohammed ṣoju fun ni iṣejọba to wa lode bayii ṣetan lati lo anfani to soodo si ẹka aṣa fun igbeleke ọrọ aje awọn eeyan orilẹede naijiria.

Image copyright AFRICAN DRUM FESTIVAL
Àkọlé àwòrán Ijọba ipinlẹ Ogun lo n ṣe agbatẹru ajọdun ilu ilẹ Afirika

Minisita feto iroyin ati aṣa gboriyin fun awọn to gbe ayẹyẹ naa kalẹ pẹlu ileri atilẹyin ijọba apapọ fun ijọba ipinlẹ Ogun lori ajọdun naa.