Ẹgbẹ́ òsèlú PDP ńgbèrò láti dà pọ̀ mọ́ àwọ́n ẹgbẹ́ míì

Kola Ologbondiyan Image copyright Kola Ologbondiyan/Facebook
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ́ òsèlú PDP ńgbèrò láti dà pọ̀ mọ́ àwọ́n ẹgbẹ́ míì

Ẹgbẹ́ òsèlú Peoples Democratic Party ńgbèrò láti yí orúkọ́ wọn padà kó tó di ìgbà ìdìbò gbogbogbò ti ọdún 2019.

Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwo ilé isẹ́ BBC pẹ̀lú akọ̀wé ẹgbẹ́ òsèlú PDP, Ọ̀gbẹ́ni Kola Ologbondiyan jẹ́ kó di mímọ̀ pé ẹgbẹ́ òsèlú PDP kàn fẹ́ dàra pọ̀ mọ̀ àwọn ẹgbẹ́ míì fún ìdìbò ọdún 2019 ni

Nínú ìwádìí míì, o hàn wípé èyí wà lára ohun tí àwọn tó fi ẹgbẹ́ náà sílẹ̀ kó tó di àkókò ìdìbò gbogbogbò ọdún 2015.

Bákan náà, ó sèè se kí èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọ́n ọ̀rọ̀ tí ẹgbẹ́ yóò fọ̀rọ̀jomitoro ọ̀rọ̀ lé lórí níbi ìpàdé pàjáwìrì ìgbìmọ̀ alásẹ́ ẹ́gbẹ́ tí wọ́n pè èyí tó wáyé nílùú Abuja.

Nínú ọ̀rọ̀ tí akọ̀wé Kola Ologbondiyan gbé jáde, o sọ wípé ìpàdé ìgbìmọ̀ alásẹ́ ẹ́gbẹ́ yóò wáyé ní ilé isẹ́ ẹ́gbẹ́ náà.

Wọ́n ní ọ̀rọ̀ orúkọ́ yóò yí pàdà tàbí kò ní yí padà yóò jẹyọ níbi ìpàdé náà. Wọ́n sì ńbojú wòó sugbọn kìí s'ohun àá dá se kó má dà bí ẹni pé bí kìí bá se òótọ́, kó má jẹ́ wípé ọgbọ́n àti si wọ́n lọ́na sáájú ìdìbò ọdún 2019 ni.

Ologbondiyan ní àwọn yóò tún wo ohun tí òfin sọ nípa rẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: