Benue- Èèyàn mẹ́wàá kú nínú ìkọ̀lù tuntun

Benue Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìkọ̀lù Benue ti di lemọ́lemọ́

Ó kéré tan, èèyàn mẹ́wàá ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn ti awọn mii náà tún farapa ninu ìkọ̀lù kan to wáyé ni ìpínlẹ̀ Benue lálẹ́ ọjọ́ Jímọ̀ mọ́júmọ́ Satide.

Ikọlu ọun ti a gbọ́ pe o sẹlẹ̀ ni awọn abúlé mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìjọba ìpínlẹ̀ Guma ni o ti mu ki ọ̀pọ̀lọpọ̀ awọn ènìyàn agbègbè ọun sa fi ilé wọn sílẹ̀.

Nigba ti o n ba BBC Yoruba sọ̀rọ̀ lori ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, ọ̀gbẹ́ni Terver Akase to jẹ́ agbẹnusọ fun Gómìnà ìpínlẹ̀ naa sọ pe, awọn afurasí Fulani darandaran ni wọn wà nídìí ìsẹ̀lẹ̀ ọ̀ún.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìjọba ìpínlẹ̀ Benue sọ pe àwọn ti lọ wo bi nnkan se sẹlẹ̀ lágbègbè naa

Akase fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pe, ẹnu ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀ún ko fi gbogbo ara tọ́rọ̀ lóri'ìkọ̀lù tó ti n wáyé lemọ́lemọ́ yii, nitori pe awọn ò lágbára lati pàsẹ fun awọn agbófinró lati gbégbèésẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ naa, nigba to jẹ́ pé ìjọba àpapọ̀ nikan ló lágbára lati se bẹ́ẹ̀.

Báwo ni ìkọ̀lù Benue se bẹ̀rẹ̀?

Lẹ́yìn tí Gomina ìpínlẹ̀ Benue, Samuel Ortom sòfin pe, ko si à n da mààlúù lójúmọmọ ni ipinlẹ ọun mọ, oun ni ìjà di lemọ́lemọ́ laarin awọn Fulani darandaran ati awọn àgbẹ̀, ti ó sì jẹ́ pe ìjà ọun ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí lọ.

Osù keji ọdún 2013 ni wọ̀n sọ pe awọn afurasí darandaran Fulani kọ́kọ́ kọlu agbègbè Agatu ti wọn si dáná sun awọ̀n ilẹ́ ni Inoli, Ologba, olegeje, olegogboche, olegede, Adana, Inminy ati Abugbe.

Lẹ́yìn ìgbà naa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ikọlu lo tun ti wáyé ni ipinlẹ Benue, ti awọn olùgbé àgbègbè naa si tún sọ pe awọn darandaran ni awọn fura si pe wọn sọsẹ̀ ọ̀ún.

Ni ọjọ́ kíní osù kíní ọdún yii ni ìkọ̀lù kan to lágbára wáyé to sì mẹ́mìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ eniyan lọ ni ipinlẹ̀ Benue ọ̀ún bakan náà.