Iléesẹ́ ààrẹ: Bùhárí padà dé lẹ́yìn ìrìnàjò sí UK

Ààrẹ Muhammadu Buhari Image copyright @AsoRock
Àkọlé àwòrán Níbi ìpàdé CHOGM, ààrẹ Bùhárí bèèrè fún àfíkún ìkóówò sí orílẹ̀èdè Nàíjíría

Iléesẹ́ ààrẹ Nàíjíríà ti kéde pé, ààrẹ Muhammadu Bùhárí ti padà dé sí orílẹ̀èdè yìí, lẹ́yìn ìrìnàjò ẹnu isẹ́ tó se sí ilẹ̀ UK, níbi tó ti báwọn péjú sí ìpàdé àwọn olórí orílẹ̀èdè tó wà nínú àjọ Commonwealth (CHOGM).

Aago méje alẹ́ ọjọ́ sátidé ló gúnlẹ̀ sí ìlú Àbújá lẹ́yìn ìrìnàjò ọlọ́jọ́ méjìlá tó se sí ìlú ọba.

Níbi ìpàdé àwọn olórí orílẹ̀èdè tó wà nínú àjọ Commonwealth (CHOGM), ni ààrẹ Bùhárí ti bèèrè fún àfíkún ìdókòòwò sí orílẹ̀èdè Nàíjíría, pẹ̀lú àfikún pé, àgbéga ètò okoòwò àti kátàkárà nìkan ni ọ̀nà tó dájú láti mú kí ọ̀pọ̀ mẹ̀kúnnù yọ nínú ìsẹ́ àti òsì.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸlẹ́wọ̀n: Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni mo ti kàwé yege ní ìdánwò Jamb

Níbẹ̀ náà ni Bùhárí ti yọ sùtì ètè sí àwọn ọ̀dọ́ ní orílẹ̀èdè Nàíjíría pé, ìdá ọgọ́ta nínú wọn ni kò lọ sílé ìwé, tí wọn sì ń jókòó kalẹ̀ pé, orílẹ̀èdè Nàíjíría ń se epo rọ̀bì, nítorí náà, àwọn ń fẹ́ owó ọ̀fẹ́ fún ìlera, ilégbèé àti ètò ẹ̀kọ́, èyí tó fa ọ̀pọ̀ awuyewuye.

Bákanáà ni ààrẹ Bùhárí tún bá olóòtú ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Theresa May sọ̀rọ̀ àti Bísọ́ọ̀bù àgbà fún Canterbury, ẹni-ọ̀wọ̀ Justin Welby.